11 Kiyesi i, nitori ohun kanna yi ti a mu nyin banujẹ fun bi ẹni ìwa-bi-Ọlọrun, iṣọra ti o mu ba nyin ti kara to, ijirẹbẹ nyin ti tó, ani irunu, ani ibẹru, ani ifẹ gbigbona, ani itara, ani igbẹsan! Ninu ohun gbogbo ẹ ti farahan pe ara nyin mọ́ ninu ọran na.
12 Nitorina, bi mo tilẹ ti kọwe si nyin, emi kò kọ ọ nitori ẹniti o ṣe ohun buburu na, tabi nitori ẹniti a fi ohun buburu na ṣe, ṣugbọn ki aniyan nyin nitori wa le farahan niwaju Ọlọrun.
13 Nitorina a ti fi itunu nyin tù wa ninu; ati ni itunu wa a yọ̀ gidigidi nitori ayọ̀ Titu, nitori lati ọdọ gbogbo nyin li a ti tu ẹmi rẹ̀ lara.
14 Bi mo tilẹ ti leri ohunkohun fun u nitori nyin, a kò dojuti mi; ṣugbọn gẹgẹ bi awa ti sọ ohun gbogbo fun nyin li otitọ, gẹgẹ bẹ̃li ori ti a lé niwaju Titu si jasi otitọ.
15 Iyọ́nu rẹ̀ si di pupọ̀ gidigidi si nyin, bi on ti nranti igbọran gbogbo nyin, bi ẹ ti fi ibẹru ati iwarìri tẹwọgbà a.
16 Mo yọ̀ nitoripe li ohun gbogbo mo ni igbẹkẹle ninu nyin.