4 Mo ni igboiya nla lati ba nyin sọ̀rọ, iṣogo mi lori nyin pọ̀, mo kun fun itunu, mo si nyọ̀ rekọja ninu gbogbo ipọnju wa.
5 Nitoripe nigbati awa tilẹ de Makedonia, ara wa kò balẹ, ṣugbọn a nwahalà wa niha gbogbo; ìja mbẹ lode, ẹ̀ru mbẹ ninu.
6 Ṣugbọn ẹniti ntù awọn onirẹlẹ ninu, ani Ọlọrun, o tù wa ninu nipa didé Titu;
7 Kì si iṣe nipa didé rẹ̀ nikan, ṣugbọn nipa itunu na pẹlu ti ẹ ti tù u ninu, nigbati o rohin fun wa ifẹ gbigbona nyin, ibanujẹ nyin, ati itara nyin fun mi; bẹni mo si tubọ yọ̀.
8 Nitoripe bi mo tilẹ fi iwe mu inu nyin bajẹ, emi kò kãbámọ̀, bi mo tilẹ ti kabamọ rí: nitoriti mo woye pe iwe nì mu nyin banujẹ, bi o tilẹ jẹ pe fun igba diẹ.
9 Emi yọ̀ nisisiyi, kì iṣe nitoriti a mu inu nyin bajẹ, ṣugbọn nitoriti a mu inu nyin bajẹ si ironupiwada: nitoriti a mu inu nyin bajẹ bi ẹni ìwa-bi-Ọlọrun, ki ẹnyin ki o maṣe tipasẹ wa pàdanù li ohunkohun.
10 Nitoripe ibanujẹ ẹni ìwa-bi-Ọlọrun a ma ṣiṣẹ ironupiwada si igbala ti kì mu abamọ wá: ṣugbọn ibanujẹ ti aiye a ma ṣiṣẹ ikú.