13 Nitori emi kò fẹ ki awọn ẹlomiran wà ni irọrun, ki o si jẹ ipọnju fun nyin,
14 Ṣugbọn nipa idọgba, pe ki ọpọlọpọ ini nyin li akoko yi le ṣe ẹkún aini wọn, ki ọ̀pọlọpọ ini wọn pẹlu le ṣe ẹkún aini nyin: ki idọgba ki o le wà:
15 Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Ẹniti o kó pọ̀ju, kò ni nkan le; ẹniti o si kó kere ju, kò ṣe alainito.
16 Ṣugbọn ọpẹ́ ni fun Ọlọrun, ẹniti o fi itara aniyan kanna yi si ọkàn Titu fun nyin.
17 Nitori on gbà ọ̀rọ iyanju nitõtọ; ṣugbọn bi o ti ni itara pipọ, on tikararẹ̀ tọ̀ nyin wá fun ara rẹ̀.
18 Awa ti rán arakunrin na pẹlu rẹ̀, iyìn ẹniti o wà ninu ihinrere yiká gbogbo ijọ.
19 Kì si iṣe bẹ̃ nikan, ṣugbọn ẹniti a ti yàn pẹlu lati ọdọ ijọ wá lati mã bá wa rìn kiri ninu ọran ore-ọfẹ yi, ti awa nṣe iranṣẹ rẹ̀ fun ogo Oluwa, ati imura-tẹlẹ wa.