1 NITORI nipa ti ipinfunni fun awọn enia mimọ́, kò ni pe mo nkọwe si nyin ju bẹ̃ lọ.
2 Nitori mo mọ̀ imura-tẹlẹ nyin, eyiti mo fi yangàn fun awọn ara Makedonia nitori nyin, pe, Akaia ti mura tan niwọn ọdún kan ti o kọja; itara nyin si ti rú ọ̀pọlọpọ soke.
3 Ṣugbọn mo ti rán awọn arakunrin, ki iṣogo wa nitori nyin ki o máṣe jasi asan niti ọ̀ran yi; pe gẹgẹ bi mo ti wi, ki ẹnyin ki o le mura tẹlẹ:
4 Bi awọn ninu ará Makedonia ba bá mi wá, ti nwọn si bá nyin li aimura tẹlẹ, ki oju ki o máṣe tì wa (laiwipe ẹnyin,) niti igbẹkẹle yi.
5 Nitorina ni mo ṣe rò pe o yẹ lati gbà awọn arakunrin niyanju, ki nwọn ki o ṣaju tọ̀ nyin wá, ki nwọn ki o si mura ẹ̀bun nyin silẹ, ti ẹ ti ṣe ileri tẹlẹ ki a le ṣe eyi na silẹ, ki o le jasi bi ohun ẹ̀bun, ki o má si ṣe dabi ti ojukòkoro.
6 Ṣugbọn eyi ni mo wipe, Ẹniti o ba funrugbin kiun, kiun ni yio ká; ẹniti o ba si funrugbin, pupọ, pupọ ni yio ká.
7 Ki olululuku enia ki o ṣe gẹgẹ bi o ti pinnu li ọkàn rẹ̀; kì iṣe àfẹ̀kùnṣe, tabi ti alaigbọdọ má ṣe: nitori Ọlọrun fẹ oninudidun ọlọrẹ.