19 Obinrin na wi fun u pe, Ọgbẹni, mo woye pe, woli ni iwọ iṣe.
20 Awọn baba wa sìn lori òke yi; ẹnyin si wipe, Jerusalemu ni ibi ti o yẹ ti a ba ma sìn.
21 Jesu wi fun u pe, Gbà mi gbọ́, obinrin yi, wakati na mbọ̀, nigbati kì yio ṣe lori òke yi, tabi Jerusalemu, li ẹnyin o ma sìn Baba.
22 Ẹnyin nsìn ohun ti ẹnyin kò mọ̀: awa nsìn ohun ti awa mọ̀: nitori igbala ti ọdọ awọn Ju wá.
23 Ṣugbọn wakati mbọ̀, o si de tan nisisiyi, nigbati awọn olusin tõtọ yio ma sìn Baba li ẹmí ati li otitọ: nitori irú wọn ni Baba nwá ki o ma sìn on.
24 Ẹmí li Ọlọrun: awọn ẹniti nsìn i ko le ṣe alaisìn i li ẹmí ati li otitọ.
25 Obinrin na wi fun u pe, mo mọ̀ pe Messia mbọ̀ wá, ti a npè ni Kristi: nigbati on ba de, yio sọ ohun gbogbo fun wa.