26 Nitoripe gẹgẹ bi Baba ti ni iye ninu ara rẹ̀; gẹgẹ bẹ̃li o si fifun Ọmọ lati ni iye ninu ara rẹ̀;
27 O si fun u li aṣẹ lati mã ṣe idajọ pẹlu, nitoriti on iṣe Ọmọ-enia.
28 Ki eyi ki o máṣe yà nyin li ẹnu; nitoripe wakati mbọ̀, ninu eyiti gbogbo awọn ti o wà ni isà okú yio gbọ́ ohùn rẹ̀.
29 Nwọn o si jade wá; awọn ti o ṣe rere, si ajinde ìye; awọn ti o si ṣe buburu, si ajinde idajọ.
30 Emi kò le ṣe ohun kan fun ara mi: bi mo ti ngbọ́, mo ndajọ: ododo si ni idajọ mi; nitori emi kò wá ifẹ ti emi tikarami, bikoṣe ifẹ ti ẹniti o rán mi.
31 Bi emi ba njẹri ara mi, ẹrí mi kì iṣe otitọ.
32 Ẹlomiran li ẹniti njẹri mi; emi si mọ̀ pe, otitọ li ẹrí mi ti o jẹ́.