14 Ṣugbọn yio san fun Tire on Sidoni nigba idajọ jù fun ẹnyin lọ.
15 Ati iwọ, Kapernaumu, a o ha gbe ọ ga de oke ọrun? a o rẹ̀ ọ silẹ de ipo-oku.
16 Ẹniti o ba gbọ́ ti nyin, o gbọ́ ti emi: ẹniti o ba si kọ̀ nyin, o kọ̀ mi; ẹniti o ba si kọ̀ mi, o kọ̀ ẹniti o rán mi.
17 Awọn adọrin na si fi ayọ̀ pada, wipe, Oluwa, awọn ẹmi èṣu tilẹ foribalẹ fun wa li orukọ rẹ.
18 O si wi fun wọn pe, Emi ri Satani ṣubu bi manamana lati ọrun wá.
19 Kiyesi i, emi fun nyin li aṣẹ lati tẹ̀ ejò ati akẽkẽ mọlẹ, ati lori gbogbo agbara ọtá: kò si si ohunkan bi o ti wù ki o ṣe, ti yio pa-nyin-lara.
20 Ṣugbọn ki ẹ máṣe yọ̀ si eyi, pe, awọn ẹmi nforibalẹ fun nyin; ṣugbọn ẹ kuku yọ̀, pe, a kọwe orukọ nyin li ọrun.