Luk 23 YCE

Wọ́n Fa Jesu Lọ Siwaju Pilatu

1 GBOGBO ijọ enia si dide, nwọn si fà a lọ si ọdọ Pilatu.

2 Nwọn si bẹ̀rẹ si ifi i sùn, wipe, Awa ri ọkunrin yi o nyi orilẹ-ede wa li ọkàn pada, o si nda wọn lẹkun lati san owode fun Kesari, o nwipe on tikara-on ni Kristi ọba.

3 Pilatu si bi i lẽre, wipe, Iwọ ha li ọba awọn Ju? O si da a lohùn wipe, Iwọ wi i.

4 Pilatu si wi fun awọn olori alufa ati fun ijọ enia pe, Emi kò ri ẹ̀ṣẹ lọwọ ọkunrin yi.

5 Nwọn si tubọ tẹnumọ ọ pe, O nrú awọn enia soke, o nkọ́ni ká gbogbo Judea, o bẹ̀rẹ lati Galili wá titi o fi de ihinyi.

6 Nigbati Pilatu gbọ́ orukọ Galili, o bère bi ọkunrin na iṣe ara Galili.

7 Nigbati o si mọ̀ pe ara ilẹ Herodu ni, o rán a si Herodu, ẹniti on tikararẹ̀ wà ni Jerusalemu li akokò na.

8 Nigbati Herodu si ri Jesu, o yọ̀ gidigidi: nitoriti o ti nfẹ ẹ ri pẹ́, o sa ti ngbọ́ ìhin pipọ nitori rẹ̀; o si tanmọ̃ ati ri ki iṣẹ iyanu diẹ ki o ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe.

9 O si bère ọ̀rọ pipọ lọwọ rẹ̀; ṣugbọn kò da a lohùn kanṣoṣo.

10 Ati awọn olori alufa ati awọn akọwe duro, nwọn si nfi i sùn gidigidi.

11 Ati Herodu ti on ti awọn ọmọ-ogun rẹ̀, nwọn kẹgan rẹ̀, nwọn si nfi i ṣẹsin, nwọn wọ̀ ọ li aṣọ daradara, o si rán a pada tọ̀ Pilatu lọ.

12 Pilatu on Herodu di ọrẹ́ ara wọn ni ijọ na: nitori latijọ ọtá ara wọn ni nwọn ti nṣe ri.

A Dá Jesu Lẹ́bi Ikú

13 Nigbati Pilatu si ti pè awọn olori alufa ati awọn olori ati awọn enia jọ,

14 O sọ fun wọn pe, Ẹnyin mu ọkunrin yi tọ̀ mi wá, bi ẹni ti o npa awọn enia li ọkàn dà: si kiyesi i, emi wadi ẹjọ rẹ̀ niwaju nyin, emi kò si ri ẹ̀ṣẹ lọwọ ọkunrin yi, ni gbogbo nkan wọnyi ti ẹnyin fi i sùn si:

15 Ati Herodu pẹlu: o sá rán a pada tọ̀ wa wá; si kiyesi i, ohun kan ti o yẹ si ikú a ko ṣe si i ti ọwọ́ rẹ̀ wá.

16 Njẹ emi ó nà a, emi ó si jọwọ rẹ̀ lọwọ lọ.

17 Ṣugbọn kò le ṣe aidá ọkan silẹ fun wọn nigba ajọ irekọja.

18 Nwọn si kigbe soke lọwọ kanna, wipe, Mu ọkunrin yi kuro, ki o si dá Barabba silẹ fun wa:

19 Ẹniti a sọ sinu tubu nitori ọ̀tẹ kan ti a ṣe ni ilu, ati nitori ipania.

20 Pilatu si tun ba wọn sọrọ, nitori o fẹ da Jesu silẹ.

21 Ṣugbọn nwọn kigbe, wipe, Kàn a mọ agbelebu, kàn a mọ agbelebu.

22 O si wi fun wọn li ẹrinkẹta pe, Ẽṣe, buburu kili ọkunrin yi ṣe? emi ko ri ọ̀ran ikú lara rẹ̀: nitorina emi o nà a, emi a si jọwọ rẹ̀ lọwọ lọ.

23 Nwọn tilẹ̀ kirimọ́ igbe nla, nwọn nfẹ ki a kàn a mọ agbelebu. Ohùn ti wọn ati ti awọn olori alufa bori tirẹ̀.

24 Pilatu si fi aṣẹ si i pe, ki o ri bi nwọn ti nfẹ.

25 O si dá ẹniti nwọn fẹ silẹ fun wọn, ẹniti a titori ọ̀tẹ ati ipania sọ sinu tubu; ṣugbọn o fi Jesu le wọn lọwọ.

A Kan Jesu Mọ́ Agbelebu

26 Bi nwọn si ti nfà a lọ, nwọn mu ọkunrin kan, Simoni ara Kirene, ti o nti igberiko bọ̀, on ni nwọn si gbé agbelebu na le, ki o mã rù u bọ̀ tẹle Jesu.

27 Ijọ enia pipọ li o ntọ̀ ọ lẹhin, ati awọn obinrin, ti npohùnrere ẹkún, ti nwọn si nṣe idarò rẹ̀.

28 Ṣugbọn Jesu yiju pada si wọn, o si wipe, Ẹnyin ọmọbinrin Jerusalemu, ẹ má sọkun fun mi, ṣugbọn ẹ sọkun fun ara nyin, ati fun awọn ọmọ nyin.

29 Nitori kiyesi i, ọjọ mbọ̀ li eyiti ẹnyin o wipe, Ibukun ni fun àgan, ati fun inu ti kò bímọ ri, ati fun ọmú ti kò funni mu ri.

30 Nigbana ni nwọn o bẹ̀rẹ si iwi fun awọn òke nla pe, Wó lù wa; ati fun awọn òke kekeke pe, Bò wa mọlẹ.

31 Nitori bi nwọn ba nṣe nkan wọnyi sara igi tutù, kili a o ṣe sara gbigbẹ?

32 Nwọn si fà awọn meji lọ pẹlu, awọn arufin, lati pa pẹlu rẹ̀.

33 Nigbati nwọn si de ibi ti a npè ni Agbari, nibẹ̀ ni nwọn gbé kàn a mọ agbelebu, ati awọn arufin na, ọkan li ọwọ́ ọtún, ati ọkan li ọwọ́ òsi.

34 Jesu si wipe, Baba, darijì wọn; nitoriti nwọn kò mọ̀ ohun ti nwọn nṣe. Nwọn si pín aṣọ rẹ̀ lãrin ara wọn, nwọn di ìbo rẹ̀.

35 Awọn enia si duro nworan. Ati awọn ijoye pẹlu wọn, nwọn nyọ-ṣùti si i, wipe, O gbà awọn ẹlomiran là; ki o gbà ara rẹ̀ là, bi iba ṣe Kristi, ayanfẹ Ọlọrun.

36 Ati awọn ọmọ-ogun pẹlu nfi i ṣe ẹlẹyà, nwọn tọ̀ ọ wá, nwọn nfi ọti kikan fun u,

37 Nwọn si nwipe, Bi iwọ ba ṣe Ọba awọn Ju, gbà ara rẹ là.

38 Nwọn si kọwe akọlé si ìgbèri rẹ̀ ni ède Hellene, ati ti Latini, ati ti Heberu, EYI LI ỌBA AWỌN JU.

39 Ati ọkan ninu awọn arufin ti a gbe kọ́ nfi ṣe ẹlẹyà wipe, Bi iwọ ba ṣe Kristi, gbà ara rẹ ati awa là.

40 Ṣugbọn eyi ekeji dahùn, o mba a wipe, Iwọ kò bẹ̀ru Ọlọrun, ti iwọ wà ninu ẹbi kanna?

41 Niti wa, nwọn jare nitori ère ohun ti a ṣe li awa njẹ: ṣugbọn ọkunrin yi kò ṣe ohun buburu kan.

42 O si wipe, Jesu, ranti mi nigbati iwọ ba de ijọba rẹ.

43 Jesu si wi fun u pe, Lõtọ ni mo wi fun ọ, Loni ni iwọ o wà pẹlu mi ni Paradise.

Ikú Jesu

44 O si to ìwọn wakati kẹfa ọjọ, òkunkun si ṣú bò gbogbo ilẹ titi o fi di wakati kẹsan ọjọ.

45 Õrùn si ṣú õkun, aṣọ ikele ti tẹmpili si ya li agbedemeji.

46 Nigbati Jesu si kigbe li ohùn rara, o ni, Baba, li ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹmí mi le: nigbati o si wi eyi tan, o jọwọ ẹmí rẹ̀ lọwọ.

47 Nigbati balogun ọrún ri ohun ti o ṣe, o yìn Ọlọrun logo, wipe, Dajudaju olododo li ọkunrin yi.

48 Gbogbo ijọ enia ti o pejọ si iran yi, nigbati nwọn nwò ohun ti nṣe, nwọn a lù ara wọn li õkan àiya, nwọn a si pada.

49 Ati gbogbo awọn ojulumọ̀ rẹ̀, ati awọn obinrin ti ntọ̀ ọ lẹhin lati Galili wá, nwọn duro li òkere, nwọn nwò nkan wọnyi.

Ìsìnkú Jesu

50 Si kiyesi i, ọkunrin kan ti a npè ni Josefu, ìgbimọ, enia rere, ati olõtọ,

51 (On kò ba wọn li ohùn ni ìmọ ati iṣe wọn), ara Arimatea, ilu awọn Ju kan, ẹniti on pẹlu nreti ijọba Ọlọrun;

52 Ọkunrin yi tọ̀ Pilatu lọ, o si tọrọ okú Jesu.

53 Nigbati o si sọ̀ ọ kalẹ, o si fi aṣọ àla dì i, o si tẹ́ ẹ sinu ibojì ti a gbẹ́ ninu okuta, nibiti a kò ti itẹ́ ẹnikẹni si ri.

54 O si ṣe ọjọ Ipalẹmọ: ọjọ isimi si kù si dẹ̀dẹ.

55 Ati awọn obinrin, ti nwọn bá a ti Galili wá, ti nwọn si tẹle, nwọn kiyesi ibojì na, ati bi a ti tẹ́ okú rẹ̀ si.

56 Nigbati nwọn si pada, nwọn pèse ohun olõrun didùn ororo ikunra ati turari tutù; nwọn si simi li ọjọ isimi gẹgẹ bi ofin.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24