Luk 13 YCE

Ẹ Ronupiwada, Bí Bẹ́ẹ̀ Kọ̀ Ẹ Óo Ṣègbé

1 AWỌN kan si wà li akokò na ti o sọ ti awọn ara Galili fun u, ẹ̀jẹ ẹniti Pilatu dàpọ mọ ẹbọ wọn.

2 Jesu si dahùn o wi fun wọn pe, Ẹnyin ṣebi awọn ara Galili wọnyi ṣe ẹlẹṣẹ jù gbogbo awọn ara Galili lọ, nitoriti nwọn jẹ irú ìya bawọnni?

3 Mo wi fun nyin, Bẹ̃kọ: bikoṣepe ẹnyin ronupiwada, gbogbo nyin ni yio ṣegbé bẹ̃ gẹgẹ.

4 Tabi awọn mejidilogun, ti ile-iṣọ ni Siloamu wólu, ti o si pa wọn, ẹnyin ṣebi nwọn ṣe ẹlẹṣẹ jù gbogbo awọn enia ti mbẹ̀ ni Jerusalemu lọ?

5 Mo wi fun nyin, Bẹ̃kọ: bikoṣepe ẹnyin ronupiwada, gbogbo nyin ni yio ṣegbé bẹ̃ gẹgẹ.

Ẹ̀kọ́ Nípa Igi Ọ̀pọ̀tọ́ Tí Kò Léso

6 O si pa owe yi fun wọn pe; ọkunrin kan ni igi ọpọtọ kan ti a gbìn si ọgbà ajara rẹ̀; o si de, o nwá eso lori rẹ̀, kò si ri nkan.

7 O si wi fun oluṣọgba rẹ̀ pe, Sawõ, lati ọdún mẹta li emi ti nwá iwò eso lori igi ọpọtọ yi, emi ko si ri nkan: ké e lulẹ; ẽṣe ti o fi ngbilẹ lasan pẹlu?

8 O si dahùn o wi fun u pe, Oluwa, jọwọ rẹ̀ li ọdún yi pẹlu, titi emi o fi tú ilẹ idi rẹ̀ yiká, titi emi o si fi bu ilẹdu si i:

9 Bi o ba si so eso, gẹgẹ: bi kò ba si so, njẹ lẹhin eyini ki iwọ ki o ke e lulẹ̀.

10 O si nkọ́ni ninu sinagogu kan li ọjọ isimi.

11 Si kiyesi i, obinrin kan wà nibẹ̀ ti o ni ẹmí ailera, lati ọdún mejidilogun wá, ẹniti o tẹ̀ tan, ti ko le gbé ara rẹ̀ soke bi o ti wù ki o ṣe.

12 Nigbati Jesu ri i, o pè e si ọdọ, o si wi fun u pe, Obinrin yi, a tú ọ silẹ lọwọ ailera rẹ.

13 O si fi ọwọ́ rẹ̀ le e: lojukanna a si ti sọ ọ di titọ, o si nyìn Ọlọrun logo.

14 Olori sinagogu si kun fun irunu, nitoriti Jesu muni larada li ọjọ isimi, o si wi fun ijọ enia pe, Ijọ mẹfa ni mbẹ ti a fi iṣiṣẹ: ninu wọn ni ki ẹnyin ki o wá ki a ṣe dida ara nyin, ki o máṣẹ li ọjọ isimi.

15 Nigbana li Oluwa dahùn, o si wi fun u pe, Ẹnyin agabagebe, olukuluku nyin ki itú malu tabi kẹtẹkẹtẹ rẹ̀ kuro nibuso, ki si ifà a lọ imu omi li ọjọ isimi?

16 Kò si yẹ ki a tú obinrin yi ti iṣe ọmọbinrin Abrahamu silẹ ni ìde yi li ọjọ isimi, ẹniti Satani ti dè, sawõ lati ọdún mejidilogun yi wá?

17 Nigbati o si wi nkan wọnyi, oju tì gbogbo awọn ọtá rẹ̀: gbogbo ijọ enia si yọ̀ fun ohun ogo gbogbo ti o ṣe lati ọwọ́ rẹ̀ wá.

Àwọn Òwe Nípa Wóró Mustardi ati Nípa Ìwúkàrà

18 O si wipe, Kini ijọba Ọlọrun jọ? kili emi o si fi wé?

19 O dabi wóro irugbin mustardi, ti ọkunrin kan mú, ti o si sọ sinu ọgbà rẹ̀; ti o si hù, o si di igi nla; awọn ẹiyẹ oju ọrun si ngbé ori ẹká rẹ̀.

20 O si tún wipe, Kili emi iba fi ijọba Ọlọrun wé?

21 O dabi iwukara, ti obinrin kan mu, ti o fi sinu oṣuwọn iyẹfun mẹta, titi gbogbo rẹ̀ o fi di wiwu.

Ẹnu Ìlẹ̀kùn Tí Ó Há

22 O si nlà arin ilu ati iletò lọ, o nkọ́ni, o si nrìn lọ si iha Jerusalemu.

23 Ẹnikan si bi i pe, Oluwa, diẹ ha li awọn ti a o gbalà? O si wi fun wọn pe,

24 Ẹ làkaka lati wọ̀ oju-ọ̀na tõro: nitori mo wi fun nyin, enia pipọ ni yio wá ọ̀na ati wọ̀ ọ, nwọn kì yio si le wọle.

25 Nigbati bãle ile ba dide lẹkan fũ, ti o ba si ti sé ilẹkun, ẹnyin o si bẹ̀rẹ si iduro lode, ti ẹ o ma kànkun, wipe, Oluwa, Oluwa, ṣí i fun wa; on o si dahùn wi fun nyin pe, Emi kò mọ̀ nyin nibiti ẹnyin gbé ti wá:

26 Nigbana li ẹnyin o bẹ̀rẹ si iwipe, Awa ti jẹ, awa si ti mu niwaju rẹ, iwọ si kọ́ni ni igboro ilu wa.

27 On o si wipe, Emi wi fun nyin, emi kò mọ̀ nyin nibiti ẹnyin gbé ti wá; ẹ lọ kuro lọdọ mi gbogbo ẹnyin ti nṣiṣẹ ẹ̀ṣẹ.

28 Ẹkún ati ipahinkeke yio wà nibẹ̀, nigbati ẹnyin o ri Abrahamu, ati Isaaki, ati Jakọbu, ati gbogbo awọn woli, ni ijọba Ọlọrun, ti a o si tì ẹnyin sode.

29 Nwọn o si ti ìla-õrùn, ati ìwọ-õrùn wá, ati lati ariwa, ati gusù wá, nwọn o si joko ni ijọba Ọlọrun.

30 Si wo o, awọn ẹni-ẹ̀hin mbẹ ti yio di ẹni-iwaju, awọn ẹni-iwaju mbẹ, ti yio di ẹni-ẹ̀hin.

Jesu Dárò Jerusalẹmu

31 Ni wakati kanna diẹ ninu awọn Farisi tọ̀ ọ wá, nwọn si wi fun u pe, Jade, ki iwọ ki o si lọ kuro nihinyi: nitori Herodu nfẹ pa ọ.

32 O si wi fun wọn pe, Ẹ lọ, ki ẹnyin si sọ fun kọ̀lọkọlọ nì pe, Kiyesi i, emi nlé awọn ẹmi èṣu jade, emi nṣe dida ara loni ati lọla, ati ni ijọ kẹta emi o ṣe aṣepe.

33 Ṣugbọn emi kò jẹ má rìn loni, ati lọla, ati li ọtunla: kò le jẹ bẹ̃ pe woli ṣegbé lẹhin odi Jerusalemu.

34 Jerusalemu, Jerusalemu, iwọ ti o pa awọn woli, ti o si sọ okuta lù awọn ti a rán si ọ pa; nigba melo li emi nfẹ iradọ bò awọn ọmọ rẹ, bi agbebọ̀ ti iradọ bò awọn ọmọ rẹ̀ labẹ́ apá rẹ̀, ṣugbọn ẹnyin kò fẹ!

35 Sawõ, a fi ile nyin silẹ fun nyin li ahoro: lõtọ ni mo si wi fun nyin, Ẹnyin ki yio ri mi, titi yio fi di akoko ti ẹnyin o wipe, Olubukun li ẹniti o mbọ̀ wá li orukọ Oluwa.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24