Luk 17 YCE

Ọ̀rọ̀ Jesu Nípa Ohun Ìkọsẹ̀

1 O SI wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ko le ṣe ki ohun ikọsẹ̀ má de: ṣugbọn egbé ni fun ẹniti o ti ipasẹ rẹ̀ de.

2 Iba san fun u ki a so ọlọ nla mọ́ ọ li ọrùn, ki a si gbé e jù sinu okun, ju ki o mu ọkan ninu awọn kekere wọnyi kọsẹ̀.

3 Ẹ mã kiyesara nyin: bi arakunrin rẹ ba ṣẹ̀, ba a wi; bi o ba si ronupiwada, dari jì i.

Ọ̀rọ̀ Jesu Nípa Ìdáríjì Ẹ̀ṣẹ̀

4 Bi o ba si ṣẹ̀ ọ li ẹrinmeje li õjọ, ti o si pada tọ̀ ọ wá li ẹrinmeje li õjọ pe, Mo ronupiwada; dari jì i.

5 Awọn aposteli si wi fun Oluwa pe, Busi igbagbọ́ wa.

6 Oluwa si wipe, Bi ẹnyin ba ni igbagbọ́ bi wóro irugbin mustardi, ẹnyin o le wi fun igi sikamine yi pe, Ki a fà ọ tú, ki a si gbìn ọ sinu okun; yio si gbọ́ ti nyin.

Òwe Iṣẹ́ Ọmọ-Ọ̀dọ̀

7 Ṣugbọn tani ninu nyin, ti o li ọmọ-ọdọ, ti o ntulẹ, tabi ti o mbọ́ ẹran, ti yio wi fun u lojukanna ti o ba ti oko de pe, Lọ ijoko lati jẹun?

8 Ti kì yio kuku wi fun u pe, Pèse ohun ti emi o jẹ, si di amure, ki iwọ ki o mã ṣe iranṣẹ fun mi, titi emi o fi jẹ ti emi o si mu tan; lẹhinna ni iwọ o si jẹ, ti iwọ o si mu?

9 On o ha ma dupẹ lọwọ ọmọ-ọdọ na, nitoriti o ṣe ohun ti a palaṣẹ fun u bi? emi kò rò bẹ̃.

10 Gẹgẹ bẹ̃li ẹnyin pẹlu, nigbati ẹ ba ti ṣe ohun gbogbo ti a palaṣẹ fun nyin tan, ẹ wipe, Alailere ọmọ-ọdọ ni wa: eyi ti iṣe iṣẹ wa lati ṣe, li awa ti ṣe.

Jesu Wo Àwọn Adẹ́tẹ̀ Mẹ́wàá Sàn

11 O si ṣe, bi o ti nlọ si Jerusalemu, o kọja larin Samaria on Galili.

12 Bi o si ti nwọ̀ inu iletò kan lọ, awọn ọkunrin adẹtẹ̀ mẹwa pade rẹ̀, nwọn duro li òkere:

13 Nwọn si nahùn soke, wipe, Jesu, Olukọni ṣãnu fun wa.

14 Nigbati o ri wọn, o wi fun wọn pe, Ẹ lọ ifi ara nyin hàn fun awọn alufa. O si ṣe, bi nwọn ti nlọ, nwọn si di mimọ́.

15 Nigbati ọkan ninu wọn ri pe a mu on larada o pada, o si fi ohùn rara yin Ọlọrun logo.

16 O si wolẹ lẹba ẹsẹ rẹ̀, o ndupẹ li ọwọ rẹ̀: ara Samaria ni on si iṣe.

17 Jesu si dahùn wipe, Awọn mẹwa ki a ṣo di mimọ́? Awọn mẹsan iyokù ha dà?

18 A ko ri ẹnikan ti o pada wá fi ogo fun Ọlọrun, bikọse alejò yi?

19 O si wi fun u pe, Dide, ki o si mã lọ: igbagbọ́ rẹ mu ọ larada.

Bí Ìjọba Yóo Ti Ṣe Dé

20 Nigbati awọn Farisi bi i pe, nigbawo ni ijọba Ọlọrun yio de, o da wọn li ohùn pe, Ijọba Ọlọrun ki iwá pẹlu àmi:

21 Bẹ̃ni nwọn kì yio wipe, Kiyesi i nihin! tabi kiyesi i lọhun! sawõ, ijọba Ọlọrun mbẹ ninu nyin.

22 O si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ọjọ mbọ̀, nigbati ẹnyin o fẹ lati ri ọkan ninu ọjọ Ọmọ-enia, ẹnyin kì yio si ri i.

23 Nwọn o si wi fun nyin pe, Wo o nihin; tabi wo o lọhun: ẹ má lọ, ẹ máṣe tẹle wọn.

24 Nitori gẹgẹ bi manamana ti ikọ li apakan labẹ ọrun, ti isi mọlẹ li apa keji labẹ ọrun: bẹ̃li Ọmọ-enia yio si ri li ọjọ rẹ̀.

25 Ṣugbọn kò le ṣaima kọ́ jìya ohun pipo, ki a si kọ̀ ọ lọdọ iran yi.

26 Bi o si ti ri li ọjọ Noa, bẹ̃ni yio ri li ọjọ Ọmọ-enia.

27 Nwọn njẹ, nwọn nmu, nwọn ngbeyawo, nwọn si nfà iyawo fun ni, titi o fi di ọjọ ti Noa wọ̀ inu ọkọ̀ lọ, kíkun omi si de, o si run gbogbo wọn.

28 Gẹgẹ bi o si ti ri li ọjọ Loti; nwọn njẹ, nwọn nmu, nwọn nrà, nwọn ntà, nwọn ngbìn, nwọn nkọle;

29 Ṣugbọn li ọjọ na ti Loti jade kuro ni Sodomu, ojo ina ati sulfuru rọ̀ lati ọrun wá, o si run gbogbo wọn.

30 Gẹgẹ bẹ̃ni yio ri li ọjọ na ti Ọmọ-enia yio farahàn.

31 Li ọjọ na, eniti o ba wà lori ile, ti ẹrù rẹ̀ si mbẹ ni ile, ki o máṣe sọkalẹ lati wá kó o; ẹniti o ba si wà li oko, ki o máṣe pada sẹhin.

32 Ẹ ranti aya Loti.

33 Ẹnikẹni ti o ba nwá ati gbà ẹmi rẹ̀ là yio sọ ọ nù; ẹnikẹni ti o ba si sọ ọ nù yio gbà a là.

34 Mo wi fun nyin, li oru ọjọ na, enia meji yio wà lori akete kan; a o mu ọkan, a o si fi ekeji silẹ.

35 Enia meji yio si ma lọ̀ ọlọ pọ̀; a o mu ọkan, a o si fi ekeji silẹ.

36 Enia meji yio wà li oko; a o mu ọkan, a o si fi ekeji silẹ.

37 Nwọn si da a lohùn, nwọn bi i pe, Nibo, Oluwa? O si wi fun wọn pe, Nibiti okú ba gbé wà, nibẹ̀ pẹlu ni idì ikojọ pọ̀ si.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24