1 O si ṣe, nigbati o wọ̀ ile ọkan ninu awọn olori Farisi lọ li ọjọ isimi lati jẹun, nwọn si nṣọ ọ.
2 Si kiyesi i, ọkunrin kan ti o li asunkun mbẹ niwaju rẹ̀.
3 Jesu si dahùn o wi fun awọn amofin ati awọn Farisi pe, O ha tọ́ lati mu-ni larada li ọjọ isimi, tabi kò tọ?
4 Nwọn si dakẹ. O si mu u, o mu u larada, o si jọwọ rẹ̀ lọwọ lọ;
5 O si dahùn o wi fun wọn pe, Tani ninu nyin ti kẹtẹkẹtẹ tabi malu rẹ̀ yio bọ sinu ihò, ti kì yio si fà a soke lojukanna li ọjọ isimi?
6 Nwọn kò si le da a li ohùn mọ́ si nkan wọnyi.
7 O si pa owe kan fun awọn ti a pè wá jẹun, nigbati o wò bi nwọn ti nyàn ipò ọlá; o si wi fun wọn pe,
8 Nigbati ẹnikan ba pè ọ wá si ibi iyawo, máṣe joko ni ipò ọlá; ki o ma ba jẹ pe, a pè ẹniti o li ọlá jù ọ lọ.
9 Nigbati ẹniti o pè ọ ati on ba de, a si wi fun ọ pe, Fun ọkunrin yi li àye; iwọ a si wa fi itiju mu ipò ẹhin.
10 Ṣugbọn nigbati a ba pè ọ, lọ ki o si joko ni ipò ẹhin; nigbati ẹniti o pè ọ ba de, ki o le wi fun ọ pe, Ọrẹ́, bọ́ soke: nigbana ni iwọ o ni iyin li oju awọn ti o ba ọ joko ti onjẹ.
11 Nitori ẹnikẹni ti o ba gbé ara rẹ̀ ga, li a o rẹ̀ silẹ; ẹnikẹni ti o ba si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ, li a o si gbéga.
12 Nigbana li o si wi fun alase ti o pè e pe, Nigbati iwọ ba se àse ọsán, tabi àse alẹ, má pè awọn ọrẹ́ rẹ, tabi awọn arakunrin rẹ, tabi awọn ibatan rẹ, tabi awọn aladugbo rẹ ọlọrọ̀; nitori ki nwọn ki o má ṣe pè ọ ẹ̀wẹ lati san ẹsan fun ọ.
13 Ṣugbọn nigbati iwọ ba se àse, pè awọn talakà, awọn alabùkù arùn, awọn amukun, ati awọn afọju:
14 Iwọ o si jẹ alabukun fun; nitori nwọn kò ni ohun ti nwọn o fi san a fun ọ: ṣugbọn a o san a fun ọ li ajinde awọn olõtọ.
15 Nigbati ọkan ninu awọn ti o ba a joko tì onjẹ gbọ́ nkan wọnyi, o wi fun u pe, Ibukun ni fun ẹniti yio jẹun ni ijọba Ọlọrun.
16 Ṣugbọn o wi fun u pe, ọkunrin kan se àse-alẹ nla, o si pè enia pipọ:
17 O si rán ọmọ-odọ rẹ̀ ni wakati àse-alẹ lati sọ fun awọn ti a ti pè wipe, Ẹ wá; nitori ohun gbogbo ṣe tan.
18 Gbogbo wọn so bẹ̀rẹ, li ohùn kan lati ṣe awawi. Ekini wi fun u pe, Mo rà ilẹ kan, emi kò si le ṣe ki ng má lọ iwò o: mo bẹ̀ ọ ṣe gafara fun mi.
19 Ekeji si wipe, Mo rà ajaga malu marun, mo si nlọ idán wọn wò: mo bẹ̀ ọ ṣe gafara fun mi.
20 Ẹkẹta si wipe, Mo gbeyawo, nitorina li emi kò fi le wá.
21 Ọmọ-ọdọ na si pada de, o sọ nkan wọnyi fun oluwa rẹ̀. Nigbana ni bãle ile binu, o wi fun ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, Jade lọ si igboro, ati si abuja ọ̀na, ki o si mu awọn talakà, ati awọn alabùkù arùn, ati awọn amukun, ati awọn afọju wá si ihinyi.
22 Ọmọ-ọdọ na si wipe, Oluwa, a ti ṣe bi o ti paṣẹ, àye si mbẹ sibẹ.
23 Oluwa na si wi fun ọmọ-ọdọ na pe, Jade lọ si opópo, ati si ọ̀na ọgbà, ki o si rọ̀ wọn lati wọle wá, ki ile mi le kún.
24 Nitori mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ninu awọn enia wọnyi ti a ti pè, ki yio tọwò ninu àse-alẹ mi.
25 Awọn ọpọ ijọ enia mba a lọ: o si yipada, o si wi fun wọn pe,
26 Bi ẹnikan ba tọ̀ mi wá, ti ko si korira baba rẹ̀, ati iya, ati aya, ati ọmọ, ati arakunrin, ati arabinrin, ani ati ẹmí ara rẹ̀ pẹlu, kò le ṣe ọmọ-ẹhin mi.
27 Ẹnikẹni ti kò ba rù agbelebu rẹ̀, ki o si ma tọ̀ mi lẹhin, kò le ṣe ọmọ-ẹhin mi.
28 Nitori tani ninu nyin ti npete ati kọ́ ile-iṣọ, ti kì yio kọ́ joko ki o ṣiro iye owo rẹ̀, bi on ni to ti yio fi pari rẹ̀.
29 Ki o ma ba jẹ pe nigbati o ba fi ipilẹ ile sọlẹ tan, ti kò le pari rẹ̀ mọ́, gbogbo awọn ti o ri i a bẹ̀rẹ si ifi i ṣe ẹlẹyà,
30 Wipe, ọkunrin yi bẹ̀rẹ si ile ikọ́, kò si le pari rẹ̀.
31 Tabi ọba wo ni nlọ ibá ọba miran jà, ti kì yio kọ́ joko, ki o si gbèro bi yio le fi ẹgbarun padegun ẹniti nmu ẹgbawa bọ̀ wá kò on loju?
32 Bi bẹ̃kọ nigbati onitọhun si wà li òkere, on a ran ikọ si i, a si bere ipinhùn alafia.
33 Gẹgẹ bẹ̃ni, ẹnikẹni ti o wù ki o ṣe ninu nyin, ti kò ba kò ohun gbogbo ti o ni silẹ, kọ̀ le ṣe ọmọ-ẹhin mi.
34 Iyọ̀ dara: ṣugbọn bi iyọ̀ ba di obu, kili a o fi mu u dùn?
35 Kò yẹ fun ilẹ, bẽni kò yẹ fun àtan; bikoṣepe ki a kó o danù. Ẹniti o ba li etí lati fi gbọ́ ki o gbọ́.