Luk 7 YCE

Jesu Wo Ọmọ Ọ̀dọ̀ Balogun Sàn

1 NIGBATI o si pari gbogbo ọ̀rọ rẹ̀ li eti awọn enia, o wọ̀ Kapernaumu lọ.

2 Ọmọ-ọdọ balogun ọrún kan, ti o ṣọwọn fun u, o ṣaisàn, o nkú lọ.

3 Nigbati o si gburó Jesu, o rán awọn agbagba Ju si i, o mbẹ̀ ẹ pe, ki o máṣai wá mu ọmọ-ọdọ on larada.

4 Nigbati nwọn si de ọdọ Jesu, nwọn fi itara bẹ̀ ẹ, wipe, O yẹ li ẹniti on iba ṣe eyi fun:

5 Nitoriti o fẹran orilẹ-ede wa, o si ti kọ́ sinagogu kan fun wa.

6 Jesu si mba wọn lọ. Nigbati kò si jìn si eti ile mọ́, balogun ọrún na rán awọn ọrẹ́ si i, wipe, Oluwa, má yọ ara rẹ lẹnu: nitoriti emi kò to ti iwọ iba fi wọ̀ abẹ orule mi:

7 Nitorina emi kò si rò pe emi na yẹ lati tọ̀ ọ wá: ṣugbọn sọ ni gbolohùn kan, a o si mu ọmọ-ọdọ mi larada.

8 Nitori emi na pẹlu jẹ ẹniti a fi si abẹ aṣẹ, ti o li ọmọ-ogun li ẹhin mi, mo wi fun ọkan pe, Lọ, a si lọ; ati fun omiran pe, Wá, a si wá; ati fun ọmọ-ọdọ mi pe, Ṣe eyi, a si ṣe e.

9 Nigbati Jesu gbọ́ nkan wọnni, ẹnu yà a si i, o si yipada si ijọ enia ti ntọ̀ ọ lẹhin, o wipe, Mo wi fun nyin, emi kò ri irú igbagbọ́ nla bi eyi ninu awọn enia Israeli.

10 Nigbati awọn onṣẹ si pada rè ile, nwọn ba ọmọ-ọdọ na ti nṣaisàn, ara rẹ̀ ti da.

Jesu Jí Ọmọ Opó Kan Dìde Ní Naini

11 O si ṣe ni ijọ keji, o lọ sí ilu kan ti a npè ni Naini; awọn pipọ ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si mba a lọ ati ọ̀pọ ijọ enia.

12 Bi o si ti sunmọ ẹnu bode ilu na, si kiyesi i, nwọn ngbé okú kan jade, ọmọ kanṣoṣo na ti iya rẹ̀, o si jẹ opó: ọ̀pọ ijọ enia ilu na si wà pẹlu rẹ̀.

13 Nigbati Oluwa si ri i, ãnu rẹ̀ ṣe e, o si wi fun u pe, Má sọkun mọ́.

14 O si wá, o si fi ọwọ́ tọ́ aga posi na: awọn ti si nrù u duro jẹ. O si wipe, Ọdọmọkunrin, mo wi fun ọ, Dide.

15 Ẹniti o kú na si dide joko, o bẹ̀rẹ si ohùn ifọ̀. O si fà a le iya rẹ̀ lọwọ.

16 Ẹ̀rù si ba gbogbo wọn: nwọn si nyìn Ọlọrun logo, wipe, Woli nla dide ninu wa; ati pe, Ọlọrun si wa ibẹ̀ awọn enia rẹ̀ wò.

17 Okikí rẹ̀ si kàn ni gbogbo Judea, ati gbogbo àgbegbe ti o yiká.

Johanu Ranṣẹ Sí Jesu

18 Awọn ọmọ-ẹhin Johanu si fi ninu gbogbo nkan wọnyi hàn fun u.

19 Nigbati Johanu si pè awọn meji ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o rán wọn sọdọ Jesu, wipe, Iwọ li ẹniti mbọ̀, tabi ki a ma reti ẹlomiran?

20 Nigbati awọn ọkunrin na si de ọdọ rẹ̀, nwọn ni, Johanu Baptisti rán wa sọdọ rẹ, wipe, Iwọ li ẹniti mbọ̀, tabi ki a ma reti ẹlomiran?

21 Ni wakati na, o si ṣe dida ara ọpọlọpọ enia ninu aisan, ati arun, ati ẹmi buburu; o si fi iriran fun ọpọlọpọ awọn afọju.

22 Jesu si dahùn o wi fun wọn pe, Ẹ pada lọ, ẹ ròhin nkan ti ẹnyin ri, ti ẹnyin si gbọ́ fun Johanu: awọn afọju nriran, awọn amukun nrìn ṣaṣa, a sọ awọn adẹtẹ̀ di mimọ́, awọn aditi ngbọran, a njí awọn okú dide, ati fun awọn òtoṣi li a nwasu ihinrere.

23 Alabukun-fun si li ẹnikẹni ti ki yio kọsẹ̀ lara mi.

24 Nigbati awọn onṣẹ Johanu pada lọ, o bẹ̀rẹ si isọ fun ijọ enia niti Johanu pe, Kili ẹnyin jade rè ijù lọ iwò? ifefe ti afẹfẹ nmì?

25 Ṣugbọn kili ẹnyin jade lọ iwò? ọkunrin ti a wọ̀ li aṣọ fẹlẹfẹlẹ? wò o, awọn ti a wọ̀ li aṣọ ogo, ti nwọn si njaiye, mbẹ li afin ọba.

26 Ṣugbọn kili ẹnyin jade lọ iwò? woli? lõtọ ni mo wi fun nyin, o si jù woli lọ.

27 Eyiyi li ẹniti a ti kọwe nitori rẹ̀ pe, Wò o, mo rán onṣẹ mi siwaju rẹ, ẹniti yio tún ọ̀na rẹ ṣe niwaju rẹ.

28 Mo wi fun nyin, ninu awọn ti a bí ninu obinrin, kò si woli ti o pọ̀ju Johanu Baptisti lọ: ṣugbọn ẹniti o kerejulọ ni ijọba Ọlọrun, o pọ̀ju u lọ.

29 Gbogbo awọn enia ti o gbọ́ ati awọn agbowode, nwọn da Ọlọrun lare, nitori a ti fi baptismu Johanu baptisi wọn.

30 Ṣugbọn awọn Farisi ati awọn amofin kọ ìmọ Ọlọrun fun ara wọn, a kò baptisi wọn lọdọ rẹ̀.

31 Oluwa si wipe, Kili emi iba fi awọn enia iran yi wé? kini nwọn si jọ?

32 Nwọn dabi awọn ọmọ kekere ti o joko ni ibi ọjà, ti nwọn si nkọ si ara wọn, ti nwọn si nwipe, Awa fùn fère fun nyin, ẹnyin kò jó; awa si ṣọ̀fọ fun nyin, ẹnyin kò sọkun.

33 Nitori Johanu Baptisti wá, kò jẹ akara, bẹ̃ni kò si mu ọti-waini; ẹnyin si wipe, O li ẹmi èṣu.

34 Ọmọ-enia de, o njẹ, o si nmu; ẹnyin si wipe, Wò o, ọjẹun, ati ọmuti, ọrẹ́ awọn agbowode ati awọn ẹlẹṣẹ!

35 Ṣugbọn a da ọgbọ́n lare lati ọdọ awọn ọmọ rẹ̀ gbogbo wá.

Jesu Dárí Ji Obinrin Ẹlẹ́ṣẹ̀ Kan

36 Farisi kan si rọ̀ ọ ki o wá ba on jẹun. O si wọ̀ ile Farisi na lọ o si joko lati jẹun.

37 Si kiyesi i, obinrin kan wà ni ilu na, ẹniti iṣe ẹlẹṣẹ, nigbati o mọ̀ pe Jesu joko njẹun ni ile Farisi, o mu oruba alabastar ororo ikunra wá,

38 O si duro tì i lẹba ẹsẹ rẹ̀ lẹhin, o nsọkun, o si bẹ̀rẹ si ifi omije wẹ̀ ẹ li ẹsẹ, o si nfi irun ori rẹ̀ nù u nù, o si nfi ẹnu kò o li ẹsẹ, o si nfi ororo kùn wọn.

39 Nigbati Farisi ti o pè e si ri i, o wi ninu ara rẹ̀ pe, ọkunrin yi iba ṣe woli, iba mọ̀ ẹni ati irú ẹniti obinrin yi iṣe ti nfi ọwọ́ kan a: nitori ẹlẹṣẹ ni.

40 Jesu si dahùn wi fun u pe, Simoni, Mo ni ohun kan isọ fun ọ. O si dahùn wipe, Olukọni, mã wi.

41 Onigbese kan wà ti o ni ajigbese meji: ọkan jẹ ẹ ni ẹdẹgbẹta owo idẹ, ekeji si jẹ ẹ ni adọta.

42 Nigbati nwọn kò si ni ti nwọn o san, o darijì awọn mejeji. Wi, ninu awọn mejeji tani yio fẹ ẹ jù?

43 Simoni dahùn o si wipe, mo ṣebi ẹniti o darijì jù ni. O si wi fun u pe, O wi i 're.

44 O si yipada si obinrin na, o wi fun Simoni pe, Iwọ ri obinrin yi? Emi wọ̀ ile rẹ, omi wiwẹ̀ ẹsẹ iwọ kò fifun mi: ṣugbọn on, omije li o fi nrọjo si mi li ẹsẹ, irun ori rẹ̀ li o fi nnù wọn nù.

45 Ifẹnukonu iwọ kò fi fun mi: ṣugbọn on, nigbati mo ti wọ̀ ile, ko dabọ̀ ẹnu ifi kò mi li ẹsẹ.

46 Iwọ kò fi oróro pa mi li ori: ṣugbọn on ti fi ororo pa mi li ẹsẹ.

47 Njẹ mo wi fun ọ, A dari ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o pọ̀ jì i; nitoriti o ni ifẹ pipọ: ẹniti a si dari diẹ jì, on na li o ni ifẹ diẹ.

48 O si wi fun u pe, A dari ẹ̀ṣẹ rẹ jì ọ.

49 Awọn ti o bá a joko njẹun si bẹ̀rẹ si irò ninu ara wọn pe, Tali eyi ti ndari ẹ̀ṣẹ jì-ni pẹlu?

50 O si dahùn wi fun obinrin na pe, Igbagbọ́ rẹ gbà ọ là; mã lọ li alafia.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24