5 Ni ilekile ti ẹnyin ba wọ̀, ki ẹ kọ́ wipe, Alafia fun ile yi.
6 Bi ọmọ alafia ba si mbẹ nibẹ̀, alafia nyin yio bà le e: ṣugbọn bi kò ba si, yio tún pada sọdọ nyin.
7 Ni ile kanna ni ki ẹnyin ki o si gbé, ki ẹ mã jẹ, ki ẹ si mã mu ohunkohun ti nwọn ba fifun nyin; nitori ọ̀ya alagbaṣe tọ́ si i. Ẹ maṣe ṣi lati ile de ile.
8 Ati ni ilukilu ti ẹnyin ba wọ̀, ti nwọn ba si gbà nyin, ẹ jẹ ohunkohun ti a ba gbé kà iwaju nyin:
9 Ẹ si mu awọn alaisan ti mbẹ ninu rẹ̀ larada, ki ẹ si wi fun wọn pe, Ijọba Ọlọrun kù dẹ̀dẹ si nyin.
10 Ṣugbọn ni ilukilu ti ẹnyin ba si wọ̀, ti nwọn kò ba si gbà nyin, nigbati ẹnyin ba si jade si igboro ilu na, ki ẹnyin ki o si wipe,
11 Ekuru iyekuru ilu nyin ti o kù si wa lara, a gbọn ọ silẹ fun nyin: ṣugbọn ẹ mọ̀ eyi pe, ijọba Ọlọrun kù dẹ̀dẹ si nyin.