9 Ẹ si mu awọn alaisan ti mbẹ ninu rẹ̀ larada, ki ẹ si wi fun wọn pe, Ijọba Ọlọrun kù dẹ̀dẹ si nyin.
10 Ṣugbọn ni ilukilu ti ẹnyin ba si wọ̀, ti nwọn kò ba si gbà nyin, nigbati ẹnyin ba si jade si igboro ilu na, ki ẹnyin ki o si wipe,
11 Ekuru iyekuru ilu nyin ti o kù si wa lara, a gbọn ọ silẹ fun nyin: ṣugbọn ẹ mọ̀ eyi pe, ijọba Ọlọrun kù dẹ̀dẹ si nyin.
12 Ṣugbọn mo wi fun nyin, yio san fun Sodomu ni ijọ na, jù fun ilu na lọ.
13 Egbé ni fun iwọ, Korasini! Egbé ni fun iwọ, Betsaida! nitori ibaṣepe a ti ṣe iṣẹ agbara ti a ṣe ninu nyin, ni Tire on Sidoni, nwọn iba ti ronupiwada lailai, nwọn iba si joko ninu aṣọ ọ̀fọ ati ninu ẽru.
14 Ṣugbọn yio san fun Tire on Sidoni nigba idajọ jù fun ẹnyin lọ.
15 Ati iwọ, Kapernaumu, a o ha gbe ọ ga de oke ọrun? a o rẹ̀ ọ silẹ de ipo-oku.