40 Nitorina ki ẹnyin ki o mura pẹlu: Nitori Ọmọ-enia mbọ̀ ni wakati ti ẹnyin kò daba.
41 Peteru si wipe, Oluwa, iwọ pa owe yi fun wa, tabi fun gbogbo enia?
42 Oluwa si dahùn wipe, Tani olõtọ ati ọlọ́gbọn iriju na, ti oluwa rẹ̀ fi jẹ olori agbo ile rẹ̀, lati ma fi ìwọn onjẹ wọn fun wọn li akokò?
43 Ibukun ni fun ọmọ-ọdọ na, nigbati oluwa rẹ̀ ba de, ti yio ba a ki o ma ṣe bẹ̃.
44 Lõtọ ni mo wi fun nyin, yio si fi i jẹ olori ohun gbogbo ti o ni.
45 Ṣugbọn bi ọmọ-ọdọ na ba wi li ọkàn rẹ̀ pe, Oluwa mi yẹ̀ igba atibọ̀ rẹ̀; ti o si bẹ̀rẹ si ilù awọn iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin, ti o si bẹ̀rẹ si ijẹ ati si imu amupara;
46 Oluwa ọmọ-ọdọ na yio de li ọjọ ti kò reti rẹ̀, ati ni wakati ti kò daba, yio si jẹ ẹ niya gidigidi, yio si yàn ipò rẹ̀ pẹlu awọn alaigbagbọ́.