25 Nwọn si wi fun u pe, Oluwa, o ni mina mẹwa.
26 Mo wi fun nyin pe, Ẹnikẹni ti o ni, li a o fifun; ati lọdọ ẹniti kò ni, eyi na ti o ni li a o gbà lọwọ rẹ̀.
27 Ṣugbọn awọn ọtá mi wọnni, ti kò fẹ ki emi ki o jọba lori wọn, ẹ mu wọn wá ihinyi, ki ẹ si pa wọn niwaju mi.
28 Nigbati o si wi nkan wọnyi tan, o lọ ṣaju, o ngòke lọ si Jerusalemu.
29 O si ṣe, nigbati o sunmọ Betfage on Betaní li òke ti a npè ni Olifi, o rán awọn meji ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀,
30 Wipe, Ẹ lọ iletò ti o kọju si nyin; nigbati ẹnyin ba nwọ̀ ọ lọ, ẹnyin o ri ọmọ kẹtẹkẹtẹ kan ti a so, ti ẹnikẹni ko gùn ri: ẹ tú u, ki ẹ si fà a wá.
31 Bi ẹnikẹni ba si bi nyin pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ntú u? ki ẹnyin ki o wi bayi pe, Oluwa ni ifi i ṣe.