27 O si ti ipa Ẹmí wá sinu tẹmpili: nigbati awọn obi rẹ̀ si gbé ọmọ na Jesu wá, lati ṣe fun u bi iṣe ofin.
28 Nigbana li o gbé e li apa rẹ̀, o fi ibukun fun Ọlọrun, o ni,
29 Oluwa, nigbayi li o to jọwọ ọmọ-ọdọ rẹ lọwọ lọ li alafia, gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ:
30 Nitoriti oju mi ti ri igbala rẹ na,
31 Ti iwọ ti pèse silẹ niwaju enia gbogbo;
32 Imọlẹ lati mọ́ si awọn Keferi, ati ogo Israeli enia rẹ.
33 Ẹnu si yà Josefu ati iya rẹ̀ si nkan ti a nsọ si i wọnyi.