3 Gbogbo awọn enia si lọ lati kọ orukọ rẹ̀ sinu iwe, olukuluku si ilu ara rẹ̀.
4 Josefu pẹlu si goke lati Nasareti ilu Galili lọ, si ilu Dafidi ni Judea, ti a npè ni Betlehemu; nitoriti iran ati idile Dafidi ni iṣe,
5 Lati kọ orukọ rẹ̀, pẹlu Maria aya rẹ̀ afẹsọna, ti o tobi fun oyún.
6 O si ṣe, nigbati nwọn wà nibẹ̀, ọjọ rẹ̀ pé ti on o bí.
7 O si bí akọbi rẹ̀ ọmọkunrin, o si fi ọja wé e, o si tẹ́ ẹ sinu ibujẹ ẹran; nitoriti àye kò si fun wọn ninu ile èro.
8 Awọn oluṣọ-agutan mbẹ ni ilu na, nwọn nṣọ agbo agutan wọn li oru ni pápá ti nwọn ngbé.
9 Sá si kiyesi i, angẹli Oluwa na yọ si wọn, ogo Oluwa si ràn yi wọn ká: ẹ̀ru si ba wọn gidigidi.