1 O si ṣe, ni ijọ kan li ọjọ wọnni, bi o ti nkọ́ awọn enia ni tẹmpili ti o si nwasu ihinrere, awọn olori alufa, ati awọn pẹlu awọn agbagbà dide sí i,
2 Nwọn si wi fun u pe, Sọ fun wa, aṣẹ wo ni iwọ fi nṣe nkan wọnyi? tabi tali o fun ọ li aṣẹ yi?
3 O si dahùn o si wi fun wọn pe, Emi pẹlu yio si bi nyin lẽre ọ̀rọ kan; ẹ sọ fun mi.
4 Baptismu ti Johanu, lati ọrun wá ni tabi lọdọ enia?