9 Nigbana li o bẹ̀rẹ si ipa owe yi fun awọn enia pe; ọkunrin kan gbìn ọgba ajara kan, o si fi ṣe agbatọju fun awọn àgbẹ, o si lọ si àjo fun igba pipẹ.
10 Nigbati o si di akokò, o rán ọmọ-ọdọ rẹ̀ kan si awọn àgbẹ na, ki nwọn ki o le fun u ninu eso ọgba ajara na: ṣugbọn awọn àgbẹ lù u, nwọn si rán a pada lọwọ ofo.
11 O si tún rán ọmọ-ọdọ miran: nwọn si lù u pẹlu, nwọn si jẹ ẹ nìya, nwọn si rán a pada lọwọ ofo.
12 O si tún rán ẹkẹta: nwọn si ṣá a lọgbẹ pẹlu, nwọn si tì i jade.
13 Nigbana li oluwa ọgba ajara wipe, Ewo li emi o ṣe? emi o rán ọmọ mi ayanfẹ lọ: bọya nigbati nwọn ba ri i, nwọn o ṣojuṣaju fun u.
14 Ṣugbọn nigbati awọn àgbẹ na ri i, nwọn ba ara wọn gbèro pe, Eyi li arole: ẹ wá, ẹ jẹ ki a pa a, ki ogún rẹ̀ ki o le jẹ ti wa.
15 Bẹ̃ni nwọn si ti i jade sẹhin ọgba ajara, nwọn si pa a. Njẹ kili oluwa ọgba ajara na yio ṣe si wọn?