10 Nigbana li o wi fun wọn pe, Orilẹ-ède yio dide si orilẹ-ède, ati ilẹ-ọba si ilẹ-ọba:
11 Isẹlẹ nla yio si wà kakiri, ati ìyan ati ajakalẹ arùn; ohun ẹ̀ru, ati àmi nla yio si ti ọrun wá.
12 Ṣugbọn ṣaju gbogbo nkan wọnyi, nwọn o nawọ́ mu nyin, nwọn o si ṣe inunibini si nyin, nwọn o fi nyin le awọn oni-sinagogu lọwọ, ati sinu tubu, nwọn o mu nyin lọ sọdọ awọn ọba ati awọn ijoye nitori orukọ mi.
13 Yio si pada di ẹrí fun nyin.
14 Nitorina ẹ pinnu rẹ̀ li ọkàn nyin pe ẹ kì yio ronu ṣaju, bi ẹ o ti dahun.
15 Nitoriti emi ó fun nyin li ẹnu ati ọgbọ́n, ti gbogbo awọn ọtá nyin kì yio le sọrọ-òdi si, ti nwọn kì yio si le kò loju.
16 A o si fi nyin hàn lati ọdọ awọn õbi nyin wá, ati awọn arakunrin, ati awọn ibatan, ati awọn ọrẹ́ wá; nwọn o si mu ki a pa ninu nyin.