47 Bi o si ti nsọ lọwọ, kiyesi i, ọ̀pọ enia, ati ẹniti a npè ni Judasi, ọkan ninu awọn mejila, o ṣaju wọn o sunmọ Jesu lati fi ẹnu kò o li ẹnu.
48 Jesu si wi fun u pe, Judasi, iwọ fi ifẹnukonu fi Ọmọ-enia hàn?
49 Nigbati awọn ti o wà lọdọ rẹ̀ ri bi yio ti jasi, nwọn bi i pe, Oluwa, ki awa ki o fi idà ṣá wọn?
50 Ọkan ninu wọn si fi idà ṣá ọmọ-ọdọ olori alufa, o si ke etí ọtún rẹ̀ sọnù.
51 Ṣugbọn Jesu dahùn o wipe, Ẹ jọwọ rẹ̀ bayi na. O si fi ọwọ́ tọ́ ọ li etí, o si wò o sàn.
52 Jesu si wi fun awọn olori alufa, ati awọn olori ẹṣọ́ tẹmpili, ati awọn agbagba, ti nwọn jade tọ̀ ọ wá, pe, Ẹnyin ha jade wá ti ẹnyin ti idà ati ọgọ bi ẹni tọ ọlọṣa wá?
53 Nigbati emi wà pẹlu nyin lojojumọ ni tẹmpili, ẹnyin ko nà ọwọ́ mu mi: ṣugbọn akokò ti nyin li eyi, ati agbara òkunkun.