1 GBOGBO ijọ enia si dide, nwọn si fà a lọ si ọdọ Pilatu.
2 Nwọn si bẹ̀rẹ si ifi i sùn, wipe, Awa ri ọkunrin yi o nyi orilẹ-ede wa li ọkàn pada, o si nda wọn lẹkun lati san owode fun Kesari, o nwipe on tikara-on ni Kristi ọba.
3 Pilatu si bi i lẽre, wipe, Iwọ ha li ọba awọn Ju? O si da a lohùn wipe, Iwọ wi i.
4 Pilatu si wi fun awọn olori alufa ati fun ijọ enia pe, Emi kò ri ẹ̀ṣẹ lọwọ ọkunrin yi.
5 Nwọn si tubọ tẹnumọ ọ pe, O nrú awọn enia soke, o nkọ́ni ká gbogbo Judea, o bẹ̀rẹ lati Galili wá titi o fi de ihinyi.