8 Nigbati Herodu si ri Jesu, o yọ̀ gidigidi: nitoriti o ti nfẹ ẹ ri pẹ́, o sa ti ngbọ́ ìhin pipọ nitori rẹ̀; o si tanmọ̃ ati ri ki iṣẹ iyanu diẹ ki o ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe.
9 O si bère ọ̀rọ pipọ lọwọ rẹ̀; ṣugbọn kò da a lohùn kanṣoṣo.
10 Ati awọn olori alufa ati awọn akọwe duro, nwọn si nfi i sùn gidigidi.
11 Ati Herodu ti on ti awọn ọmọ-ogun rẹ̀, nwọn kẹgan rẹ̀, nwọn si nfi i ṣẹsin, nwọn wọ̀ ọ li aṣọ daradara, o si rán a pada tọ̀ Pilatu lọ.
12 Pilatu on Herodu di ọrẹ́ ara wọn ni ijọ na: nitori latijọ ọtá ara wọn ni nwọn ti nṣe ri.
13 Nigbati Pilatu si ti pè awọn olori alufa ati awọn olori ati awọn enia jọ,
14 O sọ fun wọn pe, Ẹnyin mu ọkunrin yi tọ̀ mi wá, bi ẹni ti o npa awọn enia li ọkàn dà: si kiyesi i, emi wadi ẹjọ rẹ̀ niwaju nyin, emi kò si ri ẹ̀ṣẹ lọwọ ọkunrin yi, ni gbogbo nkan wọnyi ti ẹnyin fi i sùn si: