2 Nwọn si ba a, a ti yi okuta kuro li ẹnu ibojì.
3 Nigbati nwọn wọ̀ inu rẹ̀, nwọn kò si ri okú Jesu Oluwa.
4 O si ṣe, bi nwọn ti nṣe rọunrọ̀un kiri niha ibẹ̀, kiyesi i, awọn ọkunrin meji alaṣọ didan duro tì wọn:
5 Nigbati ẹ̀ru mbà wọn, ti nwọn si dojubolẹ, awọn angẹli na bi wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nwá alãye lãrin awọn okú?
6 Ko si nihinyi, ṣugbọn o jinde: ẹ ranti bi o ti wi fun nyin nigbati o wà ni Galili,
7 Pe, A ko le ṣaima fi Ọmọ-enia le awọn enia ẹlẹsẹ lọwọ, a o si kàn a mọ agbelebu, ni ijọ kẹta yio si jinde.
8 Nwọn si ranti ọ̀rọ rẹ̀.