43 O si gba a, o jẹ ẹ loju wọn.
44 O si wi fun wọn pe, Nwọnyi li ọrọ ti mo sọ fun nyin, nigbati emi ti wà pẹlu nyin pe, A kò le ṣe alaimu ohun gbogbo ṣẹ, ti a ti kọ ninu ofin Mose, ati ninu iwe awọn woli, ati ninu Psalmu, nipasẹ̀ mi.
45 Nigbana li o ṣí wọn ni iyè, ki iwe-mimọ́ ki o le yé wọn,
46 O si wi fun wọn pe, Bẹ̃li a ti kọwe rẹ̀, pe, ki Kristi ki o jìya, ati ki o si jinde ni ijọ kẹta kuro ninu okú:
47 Ati ki a wasu ironupiwada ati idariji ẹ̀ṣẹ li orukọ rẹ̀, li orilẹ-ède gbogbo, bẹ̀rẹ lati Jerusalemu lọ.
48 Ẹnyin si ni ẹlẹri nkan wọnyi.
49 Si kiyesi i, Mo rán ileri Baba mi si nyin: ṣugbọn ẹ joko ni ilu Jerusalemu, titi a o fi fi agbara wọ̀ nyin, lati oke ọrun wá.