45 Nigbana li o ṣí wọn ni iyè, ki iwe-mimọ́ ki o le yé wọn,
46 O si wi fun wọn pe, Bẹ̃li a ti kọwe rẹ̀, pe, ki Kristi ki o jìya, ati ki o si jinde ni ijọ kẹta kuro ninu okú:
47 Ati ki a wasu ironupiwada ati idariji ẹ̀ṣẹ li orukọ rẹ̀, li orilẹ-ède gbogbo, bẹ̀rẹ lati Jerusalemu lọ.
48 Ẹnyin si ni ẹlẹri nkan wọnyi.
49 Si kiyesi i, Mo rán ileri Baba mi si nyin: ṣugbọn ẹ joko ni ilu Jerusalemu, titi a o fi fi agbara wọ̀ nyin, lati oke ọrun wá.
50 O si mu wọn jade lọ titi nwọn fẹrẹ̀ de Betani, nigbati o si gbé ọwọ́ rẹ̀ soke, o sure fun wọn.
51 O si ṣe, bi o ti nsure fun wọn, a yà a kuro lọdọ wọn, a si gbé e lọ si ọrun.