7 Nigbana li o wi fun ọ̀pọ awọn enia ti o wá lati baptisi lọdọ rẹ̀ pe, Ẹnyin iran paramọlẹ, tali o kìlọ fun nyin lati sá kuro ninu ibinu ti mbọ̀?
8 Nitorina ki ẹnyin ki o so eso ti o yẹ fun ironupiwada, ki ẹ má si ṣe bẹ̀rẹ si iwi ninu ara nyin pe, awa ni Abrahamu ni baba: ki emi ki o wi fun nyin, Ọlọrun le gbe ọmọ dide fun Abrahamu ninu okuta wọnyi.
9 Ati nisisiyi pẹlu, a fi ãke le gbòngbo igi na: gbogbo igi ti kò ba so eso rere, a ke e lulẹ, a si wọ́ ọ jù sinu iná.
10 Awọn enia si mbi i pe, Kini ki awa ki o ha ṣe?
11 O dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹniti o ba li ẹ̀wu meji, ki o fi ọkan fun ẹniti kò ni; ẹniti o ba si li onjẹ, ki o ṣe bẹ̃ pẹlu.
12 Awọn agbowode si tọ̀ ọ wá lati baptisi lọdọ rẹ̀, nwọn si bi i pe, Olukọni, kili awa o ha ṣe?
13 O si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe fi agbara gbà jù bi a ti rán nyin lọ mọ́.