13 O si nà ọwọ́ rẹ̀, o fi kàn a, o ni, Mo fẹ: iwọ di mimọ́. Lọgan ẹ̀tẹ si fi i silẹ lọ.
14 O si kílọ fun u pe, ki o máṣe sọ fun ẹnikan: ṣugbọn ki o lọ, ki o si fi ara rẹ hàn fun alufa, ki o si ta ọrẹ fun iwẹnumọ́ rẹ, gẹgẹ bi Mose ti paṣẹ fun ẹrí si wọn.
15 Ṣugbọn si iwaju li okikí rẹ̀ nkàn kalẹ: ọ̀pọ ijọ enia si jumọ pade lati gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀, ati lati gbà dida ara lọdọ rẹ̀ kuro lọwọ ailera wọn.
16 O si yẹra si ijù, o si gbadura.
17 O si ṣe ni ijọ kan, bi o si ti nkọ́ni, awọn Farisi ati awọn amofin joko ni ìha ibẹ̀, awọn ti o ti ilu Galili gbogbo, ati Judea, ati Jerusalemu wá: agbara Oluwa si mbẹ lati mu wọn larada.
18 Sá si kiyesi i, awọn ọkunrin gbé ọkunrin kan ti o lẹ̀gba wá lori akete: nwọn nwá ọ̀na ati gbé e wọle, ati lati tẹ́ ẹ siwaju rẹ̀.
19 Nigbati nwọn kò si ri ọ̀na ti nwọn iba fi gbé e wọle nitori ijọ enia, nwọn gùn oke àja ile lọ, nwọn sọ̀ ọ kalẹ li alafo àja ti on ti akete rẹ̀ larin niwaju Jesu.