30 Ṣugbọn awọn akọwe, ati awọn Farisi nkùn si awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, wipe, Ẽṣe ti ẹnyin fi mbá awọn agbowode ati awọn ẹlẹṣẹ jẹ, ti ẹ mba wọn mu.
31 Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, Awọn ti ara wọn dá kò wá oniṣegun, bikoṣe awọn ti ara wọn kò da.
32 Emi kò wá ipè awọn olododo, bikoṣe awọn ẹlẹṣẹ si ironupiwada.
33 Nwọn si bi i pe, Ẽṣe ti awọn ọmọ-ẹhin Johanu fi ngbàwẹ nigbakugba, ti nwọn a si ma gbadura, gẹgẹ bẹ̃ si ni awọn ọmọ-ẹhin awọn Farisi; ṣugbọn awọn tirẹ njẹ, nwọn nmu?
34 O si wi fun wọn pe, Ẹnyin le mu ki awọn ọmọ ile iyawo gbàwẹ, nigbati ọkọ iyawo mbẹ lọdọ wọn?
35 Ṣugbọn ọjọ mbọ̀ nigbati a o gbà ọkọ iyawo lọwọ wọn, nigbana ni nwọn o si gbàwẹ ni ijọ wọnni.
36 O si pa owe kan fun wọn pẹlu pe, Kò si ẹniti ifi idãsa aṣọ titun lẹ ogbologbo ẹ̀wu; bikoṣepe titun fà a ya, ati pẹlu idãsà titun kò si ba ogbologbo aṣọ rẹ.