9 Hà si ṣe e, ati gbogbo awọn ti mbẹ pẹlu rẹ̀, fun akopọ̀ ẹja ti nwọn kó:
10 Bẹ̃ ni Jakọbu ati Johanu awọn ọmọ Sebede, ti nṣe olupẹja pọ pẹlu Simoni. Jesu si wi fun Simoni pe, Má bẹ̀ru; lati isisiyi lọ iwọ o ma mú enia.
11 Nigbati nwọn si ti mu ọkọ̀ wọn de ilẹ, nwọn fi gbogbo rẹ̀ silẹ, nwọn si tọ̀ ọ lẹhin lọ.
12 O si ṣe, nigbati o wọ̀ ilu kan, kiyesi i, ọkunrin kan ti ẹ̀tẹ bò: nigbati o ri Jesu, o wolẹ, o si mbẹ̀ ẹ, wipe, Oluwa, bi iwọ ba fẹ, iwọ le sọ mi di mimọ́.
13 O si nà ọwọ́ rẹ̀, o fi kàn a, o ni, Mo fẹ: iwọ di mimọ́. Lọgan ẹ̀tẹ si fi i silẹ lọ.
14 O si kílọ fun u pe, ki o máṣe sọ fun ẹnikan: ṣugbọn ki o lọ, ki o si fi ara rẹ hàn fun alufa, ki o si ta ọrẹ fun iwẹnumọ́ rẹ, gẹgẹ bi Mose ti paṣẹ fun ẹrí si wọn.
15 Ṣugbọn si iwaju li okikí rẹ̀ nkàn kalẹ: ọ̀pọ ijọ enia si jumọ pade lati gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀, ati lati gbà dida ara lọdọ rẹ̀ kuro lọwọ ailera wọn.