6 O si ṣe li ọjọ isimi miran, ti o wọ̀ inu sinagogu lọ, o si nkọ́ni: ọkunrin kan si mbẹ nibẹ̀ ti ọwọ́ rẹ̀ ọtún rọ.
7 Ati awọn akọwe ati awọn Farisi nṣọ ọ, bi yio mu u larada li ọjọ isimi; ki nwọn ki o le ri ọna ati fi i sùn.
8 Ṣugbọn o mọ̀ ìro inu wọn, o si wi fun ọkunrin na ti ọwọ́ rẹ̀ rọ pe, Dide, ki o si duro lãrin. O si dide duro.
9 Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Emi o bi nyin lẽre ohunkan; O tọ́ lati mã ṣe ore li ọjọ isimi, tabi lati mã ṣe buburu? lati gbà ẹmí là, tabi lati pa a run?
10 Nigbati o si wò gbogbo wọn yiká, o wi fun ọkunrin na pe, Nà ọwọ́ rẹ. O si ṣe bẹ̃: ọwọ́ rẹ̀ si pada bọ̀ sipò gẹgẹ bi ekeji.
11 Nwọn si kún fun ibinu gbigbona; nwọn si ba ara wọn rò ohun ti awọn iba ṣe si Jesu.
12 O si ṣe ni ijọ wọnni, o lọ si ori òke lọ igbadura, o si fi gbogbo oru na gbadura si Ọlọrun.