22 O si ṣe ni ijọ kan, o si wọ̀ ọkọ̀ kan lọ ti on ti awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀: o si wi fun wọn pe, Ẹ jẹ ki awa ki o rekọja lọ si ìha keji adagun. Nwọn si ṣikọ̀ lọ.
23 Bi nwọn si ti nlọ, o sùn; iji nla si de, o nfẹ li oju adagun; nwọn si kún fun omi, nwọn si wà ninu ewu.
24 Nwọn si tọ̀ ọ wá, nwọn si jí i, wipe, Olukọni, Olukọni, awa gbé. Nigbana li o dide, o si ba ẹfufu on riru omi wi: nwọn si da, idakẹ-rọrọ si de.
25 O si wi fun wọn pe, Igbagbọ́ nyin dà? Bi ẹ̀ru ti mba gbogbo wọn, ti hà si nṣe wọn, nwọn mbi ara wọn pe, irú ọkunrin kili eyi! nitori o ba ẹfufu on riru omi wi, nwọn si gbọ́ tirẹ̀.
26 Nwọn si gúnlẹ ni ilẹ awọn ara Gadara, ti o kọju si Galili.
27 Nigbati o si sọkalẹ, ọkunrin kan pade rẹ̀ li ẹhin ilu na, ti o ti ni awọn ẹmi èṣu fun igba pipẹ, ti kì iwọ̀ aṣọ, bẹ̃ni kì ijoko ni ile kan, bikoṣe ni ìboji.
28 Nigbati o ri Jesu, o ke, o wolẹ niwaju rẹ̀, o wi li ohùn rara, pe, Kini ṣe temi tirẹ Jesu, iwọ Ọmọ Ọlọrun Ọgá-ogo? emi bẹ̀ ọ máṣe da mi loró.