24 Nwọn si tọ̀ ọ wá, nwọn si jí i, wipe, Olukọni, Olukọni, awa gbé. Nigbana li o dide, o si ba ẹfufu on riru omi wi: nwọn si da, idakẹ-rọrọ si de.
25 O si wi fun wọn pe, Igbagbọ́ nyin dà? Bi ẹ̀ru ti mba gbogbo wọn, ti hà si nṣe wọn, nwọn mbi ara wọn pe, irú ọkunrin kili eyi! nitori o ba ẹfufu on riru omi wi, nwọn si gbọ́ tirẹ̀.
26 Nwọn si gúnlẹ ni ilẹ awọn ara Gadara, ti o kọju si Galili.
27 Nigbati o si sọkalẹ, ọkunrin kan pade rẹ̀ li ẹhin ilu na, ti o ti ni awọn ẹmi èṣu fun igba pipẹ, ti kì iwọ̀ aṣọ, bẹ̃ni kì ijoko ni ile kan, bikoṣe ni ìboji.
28 Nigbati o ri Jesu, o ke, o wolẹ niwaju rẹ̀, o wi li ohùn rara, pe, Kini ṣe temi tirẹ Jesu, iwọ Ọmọ Ọlọrun Ọgá-ogo? emi bẹ̀ ọ máṣe da mi loró.
29 (Nitoriti o ti wi fun ẹmi aimọ́ na pe, ki o jade kuro lara ọkunrin na. Nigbakugba ni isá ma mu u: a si fi ẹ̀wọn ati ṣẹkẹṣẹkẹ dè e; o si da gbogbo ìde na, ẹmi èṣu na si dari rẹ̀ si ijù.)
30 Jesu si bi i pe, Orukọ rẹ? o si dahùn pe, Legioni: nitoriti ẹmi eṣu pipọ wọ̀ ọ lara lọ.