33 O si ṣe, nigbati nwọn lọ kuro lọdọ rẹ̀, Peteru wi fun Jesu pe, Olukọni, o dara fun wa ki a mã gbé ihinyi: jẹ ki awa ki o pa agọ́ mẹta; ọkan fun iwọ, ati ọkan fun Mose, ati ọkan fun Elijah: kò mọ̀ eyi ti o nwi.
34 Bi o ti nsọ bayi, ikũkũ kan wá, o ṣiji bò wọn: ẹ̀ru si ba wọn nigbati nwọn nwọ̀ inu ikuku lọ.
35 Ohùn kan si ti inu ikũkũ wá, o ni, Eyiyi li ayanfẹ Ọmọ mi: ẹ mã gbọ́ tirẹ̀.
36 Nigbati ohùn na si dakẹ, Jesu nikanṣoṣo li a ri. Nwọn si pa a mọ́, nwọn kò si sọ ohunkohun ti nwọn ri fun ẹnikẹni ni ijọ wọnni.
37 O si ṣe, ni ijọ keji, nigbati nwọn sọkalẹ lati ori òke wá, ọ̀pọ awọn enia wá ipade rẹ̀.
38 Si kiyesi i, ọkunrin kan ninu ijọ kigbe soke, wipe, Olukọni, mo bẹ̀ ọ, wò ọmọ mi; nitori ọmọ mi kanṣoṣo na ni.
39 Si kiyesi i, ẹmi èṣu a ma mu u, a si ma kigbe lojijì; a si ma nà a tàntàn titi yio fi yọ ifofó li ẹnu, a ma pa a lara, a tilẹ fẹrẹ má fi i silẹ lọ.