5 Iye awọn ti kò ba si gbà nyin, nigbati ẹnyin ba jade kuro ni ilu na, ẹ gbọ̀n ekuru ẹsẹ nyin fun ẹrí si wọn.
6 Nwọn si jade, nwọn nlà iletò lọ, nwọn si nwasu ihinrere, nwọn si nmu enia larada nibi gbogbo.
7 Herodu tetrarki si gbọ́ nkan gbogbo ti nṣe lati ọdọ rẹ̀ wá: o si damu, nitoriti awọn ẹlomiran nwipe, Johanu li o jinde kuro ninu okú;
8 Awọn ẹlomiran si wipe Elijah li o farahàn; ati awọn ẹlomiran pe, ọkan ninu awọn woli atijọ li o jinde.
9 Herodu si wipe, Johanu ni mo ti bẹ́ lori: ṣugbọn tali eyi, ti emi ngbọ́ irú nkan wọnyi si? O si nfẹ lati ri i.
10 Nigbati awọn aposteli si pada de, nwọn ròhin ohun gbogbo fun u ti nwọn ti ṣe. O si mu wọn, o si lọ si apakan nibi ijù si ilu ti a npè ni Betsaida.
11 Nigbati ọpọ enia si mọ̀, nwọn tẹle e: o si gbà wọn, o si sọ̀rọ ijọba Ọlọrun fun wọn; awọn ti o fẹ imularada, li o si mu larada.