18 Réhóbóámù fẹ́ Máhálátì tí ó jẹ́ ọmọbìnrin ọmọkùnrin Dáfídì Jérímótì àti ti Ábíháílì, ọmọbìnrin ọmọkùnrin ti Jésè Élíábì.
19 Ó bí àwọn ọmọ fún un: Jéúṣì, Ṣémáríà àti Ṣáhámì.
20 Nígbà náà ó fẹ́ Mákà ọmọbìnrin Ábúsálómù, tí ó bí Ábíjà fún Átáì, Ṣíṣà àti Ṣélómítì.
21 Réhóbóámù fẹ́ràn Mákà ọmọbìnrin Ábúsálómù ju èyí kejì nínú àwọn ìyàwó rẹ̀ àti àwọn àlè rẹ̀ lọ. Ní gbogbo rẹ̀, ó ní ìyàwó méjìdínlógún àti ọgọ́ta àlè ọmọkùnrin méjìdínlọ́gbọ̀n àti ọgọ́ta ọmọbìnrin.
22 Réhóbóámù yan Ábíjà ọmọ Mákà láti jẹ́ olóyè ọmọ aládé láàárin àwọn arákùnrin rẹ̀, kí ó ba à lè ṣe é ní ọba.
23 Ó hùwà ọlọ́gbọ́n, nípa fí fọ́nká díẹ̀ nínú àwọn ọmọ rẹ̀ jákè jádò ká àwọn agbégbé Júdà àti Bẹ́ńjámínì àti sí gbogbo àwọn ìlú ńlá aláàbò. Ó fún wọn ní ọ̀pọ̀ ohun tí wọ́n fẹ́, ó sì gba ọ̀pọ̀ ìyàwó fún wọn.