2 Kíróníkà 27 BMY

Jótámù Ọba Júdà

1 Jótámù sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó jẹ ọba, ó sì di ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mẹ́rìndínlógun. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Jérúsà ọmọbìnrin Sádókì.

2 Ó sì ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ Ùsáyà ti ṣe, ṣùgbọ́n kìkì wí pé kò wọ ilé Olúwa. Àwọn ènìyàn síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n ń se iṣẹ́ ibi wọn.

3 Jótanì sì kọ́ ẹnu ọ̀nà gíga ilé Olúwa ó sì ṣe iṣẹ́ lórí odi ni pẹ̀tẹ́lẹ̀ Óféli.

4 Ó sì kọ́ àwọn ìlú ní Júdà òkè àti nínú igbó àti ilé ìsọ́, ó mọ ilé odi.

5 Jótanì sì ṣẹ́ ogun lórí ọba àwọn ará Ámónì ó sì borí wọn. Ní ọdún náà àwọn ará Ámórì wọ́n sì san fún ọgọ́rùn-ún tálẹ́ńtì fàdákà àti ẹgbàaàrún òsùwọ̀n àlìkámà àti ẹgbàárún balì. Àwọn ará Ámónì gbé e wá ní iye kan náà àti pẹ̀lú ní ọdún kejì àti ní ọdún kẹta.

6 Jótamù sì di alágbára nítorí ó rìn ní ọ̀nà tótọ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀.

7 Ìyòókù iṣẹ́ ìjọba Jótamù, pẹ̀lú gbogbo àwọn ogun rẹ̀ pẹ̀lú ohun mìíràn tí ó ṣe, ni a kọ sínú ìwé àwọn ọba Ísírẹ́lì àti ti Júdà.

8 Ó sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n nígbà tí ó jẹ ọba, ó sì jẹ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mẹ́rìndínlógún.

9 Jótamù sì sùn pẹ̀lú àwọn baba a rẹ̀ a sì sin ín ní ìlú Dáfídì, Áhásì ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34 35 36