2 Kíróníkà 24 BMY

Jóásì Tún Ilé Olúwa Ṣe.

1 Jóásì jẹ́ ọmọ ọdún méje nígbà tí ó jẹ ọba, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ogójì ọdún. Orúkọ ìya rẹ̀ ni Ṣíbíà ti Béríṣébà.

2 Jóásì ṣe ohun tí ó dára ní ojú Olúwa ní gbogbo àkókò Jéhóiádà àlùfáà.

3 Jéhóiádà yan ìyàwó méjì fún-un, ó sì ní àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin.

4 Ní àkókò kan, Jóásì pinnu láti tún ilé Olúwa ṣe.

5 Ó pe Àwọn Àlùfáà àti àwọn ará Léfì jọ, ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sí àwọn ìlú Júdà, kí ẹ sì gba owó ìtọ̀sì lati ọwọ́ gbogbo Ísírẹ́lì láti fi tún ilé Ọlọ́run ṣe, ṣé nísinsìn yìí” Ṣùgbọ́n àwọn ará Léfì kò ṣe é lẹ́ẹ́kan naà.

6 Nítorí náà ọba paálásẹ fún Jéhóiádà olorí àlùfáà ó sì wí fún-un pé, “Kí ni ó dé tí o kò, bèèrè lọ́wọ́ àwọn ará Léfì láti mú wá láti Júdà àti Jérúsálẹ́mù, owó orí tí Mósè ìránṣẹ́ Olúwa ti fi lélẹ̀ àti nípasẹ̀ àpéjọ gbogbo Ísírẹ́lì fún àgọ́ ìjẹ́rìí?”

7 Nísinsinyí, àwọn ọmọkùnrin, obìnrin búburú ni Ataláyà ti fọ́ ilé Ọlọ́run, ó sì ti lo àwọn nǹkan ìyàsọ́tọ̀ fún àwọn Báálì.

8 Nípasẹ̀ ọba, a ṣe àpótí wọ́n sì gbé e sí ìta, ní ẹnu ọ̀nà ilé Olúwa.

9 A ṣe ìkéde ní Júdà àti Jérúsálẹ́mù wí pé wọ́n gbọdọ̀ mú wá fún Olúwa, owó orí tí Mósè ìránṣẹ́ Olúwa ti bèèrè lọ́wọ́ Ísírẹ́lì ní ihà.

10 Gbogbo àwọn ènìyàn mú gbogbo ìdá owó ti wọn wá pẹ̀lú ìdùnnú, wọ́n ń jù ú sínú àpótí títí tí ó fi kún.

11 Nígbà kígbà tí a bá gbé àpótí wọlé láti ọwọ́ àwọn ará Léfì sí ọwọ́ àwọn ìjòyè ọba, tí wọ́n bá sì rí wí pe owó ńlá wà níbẹ̀ àwọn akọ̀wé ọna àti ìjòyè olórí àlùfáà yóò wá láti kó owó rẹ̀ kúrò, wọn yóò sì dá a padà sí àyè rẹ̀. Wọ́n ṣe èyí déédéé, wọ́n sì kó iye owó ńlá.

12 Ọba àti Jéhóiádà fi fún àwọn ọkùnrin náà tí ó gbé iṣẹ́ náà jáde ti a bèrè fún ilé Olúwa. Wọ́n fi owó gba ẹni tí ń fi òkúta mọ ilé àti àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà láti kọ́ ilé Olúwa padà, àti àwọn òsìsẹ́ pẹ̀lú irin àti idẹ láti tún ilé Olúwa ṣe.

13 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ náà, sì lọ ṣíwájú àti síwajú ní ọwọ́ wọn, wọ́n sì tún mú ilé Ọlọ́run dúró sí ipò rẹ̀, wọ́n mún un le.

14 Nígbà tí wọ́n sì parí rẹ̀ tán, wọ́n mú owó ìyókù wá sí iwájú ọba àti Jéhóíádà, a sì fi ohun èlò fún ilé Olúwa, àní ohun èlò fún ìsìn àti fún ẹbọ pẹ̀lú ọpọ́n, àni ohun èlò wúrà àti fàdákà. Wọ́n sì ń rú ẹbọ sísun ní ilé Olúwa nígbà gbogbo ní gbogbo ọjọ́ Jéhóiádà.

Ikú Jéhóiádà

15 Ṣùgbọ́n Jéhóiádà di arúgbó, ó sì kún fún ọjọ́, ó sì kú, ẹni àádóje ọdún ni nígbà tí ó kú.

16 Wọ́n sì sin ín ní ìlú Dáfídì pẹ̀lú àwọn ọba, nítorí tí ó ṣe rere ní Ísírẹ́lì, àti sí Ọlọ́run àti sí ilé rẹ̀.

Ìwà Búburú Jóásì.

17 Lẹ́yìn ikú Jéhóíadà, àwọn onisẹ́ Júdà wá láti fi ìforíbalẹ̀ wọn hàn sí ọba. Ó sì fèsì sí wọn.

18 Wọ́n pa ilé Olúwa tì, Ọlọ́run baba a wọn. Wọ́n sì ń sin àwọn òpó Áṣérà àti àwọn òrìṣà. Nítorí ẹbí wọn, ìbínu Ọlọ́run dé sórí Júdà àti Jérúsálẹ́mù.

19 Bí ó ti wù kí ó rí, Olúwa rán àwọn wòlíì sí àwọn ènìyàn láti mú wọn padà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, wọ́n jẹ́rìí nípa wọn, wọn kì yóò gbọ́.

20 Nígbà náà, ẹ̀mí Ọlọ́run wá sórí Ṣákáríhà ọmọ Jéhóíádà wòlíì, ó dúró níwájú àwọn ènìyàn ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Kí ni ó dé tí ẹ̀yin kò fi tẹ̀lé àṣẹ Olúwa? Ìwọ kì yóò ṣe rere. Nítorí tí ìwọ ti kọ Olúwa sílẹ̀, òun pẹ̀lú ti kọ̀ yín sílẹ̀.’ ”

21 Ṣùgbọ́n wọ́n dìtẹ̀ sí i, àti nípa àṣẹ ọba, wọ́n sọ ọ́ lókúta pa nínú àgbàlá ààfin ilé Olúwa

22 Ọba Jóáṣì kò rántí inú rere tí Jéhóiádà baba Ṣakaráyà ti fi hàn án ṣùgbọ́n, ó pa ọmọ rẹ̀, tí ó wí bí ó ti ń kú lọ pé, “Kí Olúwa kí ó rí èyí kí ó sì pè ọ́ sí ìṣírò.”

23 Ní òpin ọdún, àwọn ọmọ ogun Árámì yàn láti dojúkọ Jóáṣì; wọ́n gbógun ti Júdà àti Jérúsálẹ́mù, wọ́n sì pa gbogbo àwọn asáájú àwọn ènìyàn. Wọ́n rán gbogbo àwọn ìkógun sí ọba wọn ní Dámásíkọ́sì.

24 Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ọmọ ogun Árámì ti wá pẹ̀lú àwọn ọkùnrin díẹ̀ Olúwa sì fi ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ogun lé wọn lọ́wọ́, nítorí tí Júdà ti kọ Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn sílẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ṣe ìdájọ́ Jóásì.

25 Nígbà tí àwọn ará Árámù kúrò, wọ́n fi Jóásì sílẹ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ọgbẹ́. Àwọn onísẹ́ rẹ̀ dìtẹ̀ si fún pípa ọmọ Jéhóiádà àlùfáà, wọ́n sì pa á ní orí ibùsùn rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ó sì kú, a sì sin ín sínú ìlú ńlá ti Dáfídì, ṣùgbọ́n kì í ṣe nínú àwọn ibojì àwọn ọba.

26 Àwọn tí ó dìtẹ̀ sì jẹ́ Ṣábádì, ọmọ Ṣíméátì arábìnrin Ámónì àti Jóhéṣábádì ọmọ Ṣímírítì arábìnrin Móábì.

27 Àkọsílẹ̀ àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn ọ̀pọ̀ lọ́pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀, àti àkọsílẹ̀ ti ìmúpadà sípò ilé Ọlọ́run ní a kọ sínú ìwe ìtumọ̀ ti àwọn ọba. Ámásáyà ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34 35 36