2 Kíróníkà 17 BMY

Jehóṣáfátì Ọba Júdà

1 Jehóṣáfátì ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀ ó sì mú arà rẹ̀ lágbára sí lórí Ísírẹ́lì.

2 Ó sì fi ogun sínú gbogbo ìlú olódi Júdà ó sì kó ẹgbẹ́ ológun ní Júdà àti nínú ìlú Éfúráímù tí baba rẹ̀ ti gbà.

3 Olúwa sì wà pẹ̀lú Jéhóṣáfátì nítorí, ní ọdún àkọ́kọ́ rẹ̀, ó rìn ní ọ̀nà ti baba rẹ̀ Dáfídì ti rìn, kò sì fi ọ̀ràn lọ Báálímù.

4 Sùgbọ́n ó wá Ọlọ́run baba rẹ̀ kiri ó sì tẹ̀lẹ́ àṣẹ rẹ̀ ju iṣẹ́ Ísírẹ́lì.

5 Olúwa sì fi ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ lábẹ́ àkóso rẹ̀, gbogbo Júdà sì mú ẹ̀bùn wá fún Jehóṣáfátì, Bẹ́ẹ̀ ni ó sì ní ọrọ̀ àti ọlá lọ́pọ̀lọpọ̀.

6 Ọkàn rẹ̀ sì gbé sokè si ọ̀nà Olúwa, pẹ̀lúpẹ̀lù, ó sì mú ibi gíga wọn àti òrìṣà kúrò ní Júdà.

7 Ní ọdún kẹta ìjọba rẹ̀, ó rán àwọn ìjòyè rẹ̀ Bẹni-Háílì, Obádíà Sekaríà, Nètaníélì Míkíà láti máa kọ́ ni nínú ìlú Júdà.

8 Wọ́n sì ní díẹ̀ lára àwọn ọmọ Léfì, àní Ṣémáyà, Netaníà, Sebadíà, Ásáélì, Ṣémírámótì, Jéónátanì, Àdóníjà, Tóbíyà àti Tobi-Àdóníjà àti àwọn àlùfáà Élíṣámà àti Jéhórámù.

9 Wọ́n ń kọ́ ni ní agbégbé Júdà, wọ́n mú ìwé òfin Olúwa dání, wọ́n sì rìn yíká gbogbo àwọn ìlú Júdà wọ́n sì ń kọ́ àwọn ènìyàn.

10 Ìbẹ̀rù Olúwa bà lórí gbogbo ìjọba ilẹ̀ tí ó yí Júdà ká, débi pé wọn kò bá Jéhóṣáfátì jagun.

11 Lára àwọn ará Fílístínì, mú ẹ̀bùn fàdákà gẹ́gẹ́ bí owó ọba wá fún Jéhóṣáfátì, àwọn ará Árábíà sì mú ọ̀wọ́ ẹran wá fún-un, ẹgbàrin ó dín ọ̀dúnrún àgbò àti ẹgbarìndín ní ọ̀ọ́dúnrún òbúkọ.

12 Jéhóṣáfátì sì ń di alágbára nínú agbára síi, ó sì kọ́ ilé olódi àti ilé ìsúra púpọ̀ ní Júdà

13 Ó sì ní ìṣúra ní ìlu Júdà. Ó sì tún ní àwọn alágbára jagunjagun akọni ọkùnrin ní Jérúsálẹ́mù.

14 Iye wọn gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn nì wọ̀nyí:Láti Júdà, àwọn olórí ìsùkan ti ẹgbẹ̀rún (1,000):Ádínà olórí, pẹ̀lú ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀dó gún alágbára akọni ọkùrin (300, 00);

15 Èkejì Jéhósáfátì olórí, pẹ̀lú ọ̀kẹ́ mẹ́rìnlá ọkùnrin (280,000);

16 Àtẹ̀lé Ámásíà ọmọ Síkírì, ẹni tí ó fi ara rẹ̀ fún iṣẹ́ Olúwa pẹ̀lú ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000).

17 Láti ọ̀dọ̀ Bẹ́ńjámínì:Élíádà, alágbára akọni ọkùnrin pẹ̀lú ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000) àwọn jagunjagun ọkùnrin pẹ̀lú ọrun àti àpáta ìhámọ́ra;

18 Àtẹ̀lé Jéhósábádì, pẹ̀lú ọ̀kẹ́ mẹ́sàn án (180,000) jagunjagun ọkùnrin múra sílẹ̀ fún ogun.

19 Wọ̀nyí ni àwọn ọkùnrin tí ń dúró níwáju ọba, ní àyíká àwọn ẹni tí ó fi sínú ìlú olódi ní àyíká gbogbo Júdà.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34 35 36