2 Kíróníkà 9 BMY

Ọbabìnrin Ṣébà Bẹ Sólómónì Wò

1 Nígbà tí ayaba Ṣébà gbọ́ nípa òkìkí Sólómónì, ó sì wá sí Jérúsálẹ́mù láti dán-an-wò pẹ̀lú ìbéèrè tí ó le. Ó dé pẹ̀lú ẹgbẹ́ ńlá kan pẹ̀lú ìbákasíẹ tí ó ru tùràrí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ iye wúrà, àti òkúta iyebíye, ó wá sí ọ̀dọ̀ Sólómónì ó sì sọ̀rọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nípa gbogbo ohun tí ó ní lọ́kàn rẹ̀.

2 Sólómónì sì dáa lóhùn gbogbo ìbéèrè rẹ̀; kò sì sí èyíkéyìí tí kò lè ṣe àlàyé fún.

3 Nígbà tí ayaba Ṣébà rí ọgbọ́n Sólómónì àti pẹ̀lu ilé tí ó ti kọ́,

4 Oúnjẹ tí ó wà lórí tábìlì rẹ̀, àti ìjòkòó àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti dídúró àwọn ìránṣẹ́ nínú aṣọ wọn, àti àwọn agbọ́tí nínú aṣọ wọn àti ẹbọ ọrẹ sísun tí ó ṣe ní ilé Olúwa, ó sì ní ìdálágara.

5 Ó sì wí fún ọba pé, “Ìròyìn tí mo gbọ́ ní ìlú mi nípa iṣẹ́ rẹ àti ọgbọ́n rẹ, òtítọ́ ni.

6 Ṣùgbọ́n èmi kò gba ohun tí wọ́n sọ gbọ́ àyàfi ìgbà tí mó dé ibí tí mo sì ri pẹ̀lú ojú mi. Nítòótọ́, kì í tilẹ̀ ṣe ìdàjọ́ ìdajì títóbi ọgbọ́n rẹ ní a sọ fún mi: ìwọ ti tàn kọ já òkìkí tí mo gbọ́.

7 Báwo ni inú àwọn ọkùnrin rẹ ìbá ṣe dùn tó! Báwó nínú dídùn àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn tí n dúró nígbà gbogbo níwájú rẹ láti gbọ́ ọgbọ́n rẹ!

8 Ìyìn lóyẹ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó ní inú dídùn nínú rẹ tí ó sì gbé ọ ka orí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ láti jẹ ọba fún Olúwa Ọlọ́run rẹ. Nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run rẹ fún Ísírẹ́lì láti fi ìdí wọn kalẹ̀ láéláé, ó sì ti fi ọ́ ṣe ọba lórí wọn, láti ṣe ìdájọ́ àti òtítọ́.”

9 Nígbà náà ni ó sì fún ọba ní ọgọ́fà talẹ́ntì wúrà (120). Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iye tùràrí, àti òkúta iyebíye. Kò sì tíì sí irú tùràrí yí gẹ́gẹ́ bí èyí tí ayaba Ṣébà fifún ọba Sólómónì.

10 Àwọn ènìyàn Húrámù àti àwọn ọkùnrin Sólómónì gbé wúrà wá láti Ófírì, wọ́n sì tún gbé igi álígúmù pẹ̀lú àti òkúta iyebíye wá.

11 Ọba sì lo igi álígúmù náà láti fi ṣe àtẹ̀gùn fún ilé Olúwa àti fún ilé ọba àti láti fi ṣe dùùrù àti ohun ọ̀nà orin fún àwọn akọrin. Kò sì sí irú rẹ̀ tí a ti rírí ní ilẹ̀ Júdà.

12 Ọba Sólómónì fún ayaba Ṣébà ní gbogbo ohun tí ó bèèrè fún àti ohun tí ó wù ú; ó sì fi fún un ju èyí tí ó mú wá fún un lọ. Nígbà náà ni ó lọ ó sì padà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sí ìlú rẹ̀.

Dídán Sólómónì

13 Ìwọ̀n wúrà tí Sólómónì gbà ní ọdún kan sì jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́fà talẹ́ntì (666),

14 Láì tíì ka àkójọpọ̀ owó ìlú tí ó wọlé láti ọ̀dọ̀ àwọn oníṣòwò àti àwọn ọlọ́jà. Àti pẹ̀lú gbogbo àwọn ọba Árábíà àti àwọn báálẹ̀ ilẹ̀ náà mu wúrà àti fàdákà wá fún Sólómonì.

15 Ọba Solómónì sì ṣe igba (200) àṣà wúrà lílù: ẹgbẹ̀ta (6,000) àsà tí a fi òlùlù wúrà sí òkànkàn sékélì.

16 Ó sì ti ṣe ọ̀ọ́dúnrún (300) kékeré ṣékélì tí a fi òlù lù wúrà, pẹ̀lú ọ̀ọ́dúnrún (3,000) sékélì wúrà nínú àpáta kọ̀kan. Ọba sì kó wọn sínú ilé ti igbó Lébánónì.

17 Nígbà náà ọba sì ṣe ìtẹ́ pẹ̀lú èyín erin ńlá kan ó sì fi wúrà tó mọ́ bò ó.

18 Ìtẹ́ náà sì ní àtẹ̀gùn mẹ́fà, àti pẹ̀lú àpóti ìtìsẹ̀ wúrà kan ni a dè mọ́ ọn. Ní ìhá méjèèjì ibi ìjókòó ní ó ní ìropá, pẹ̀lú kìnnìun tí ó dúró lẹ́bàá olúkúlùkù wọn.

19 Kìnnìún méjìlá dúró lórí àtẹ̀gùn mẹ́ta, ọ̀kan àti ní ìhà olúkúlùkù àtẹ̀gùn kò sì sí irú rẹ̀ tí a ti ṣe rí fún ìjọba mìíràn.

20 Gbogbo ohun èlò mímú ìjọba Solómónì ni ó jẹ́ kìkì wúrà, àti gbogbo ohun èlò agbo ilé ní ibi igbó Lébánonì ni ó jẹ́ wúrà mímọ́. Kò sì sí èyí tí a fi fàdákà ṣe, nítorí a kò ka fàdákà sí nǹkan kan ní gbogbo ọjọ́ Sólómónì.

21 Ọba ní ọkọ̀ tí a fi ń tajà tí àwọn ọkùnrin Húrámù ń bojútó. Ẹ̀kan ní ọdún mẹ́ta ni ó máa ń padà, ó ń gbé wúrà àti fàdákà àti eyín erin, àti ìnàkí àti ẹyẹ ológe wá.

22 Ọba Solómónì sì tóbi nínú ọlá ńlá àti ọgbọ́n ju gbogbo àwọn ọba tí ó kù lórí ilẹ̀ ayé lọ.

23 Gbogbo àwọn ọba ayé ń wá ojú rere lọ́dọ̀ Sólómónì láti gbọ́n ọgbọ́n tí Ọlọ́run ti fi sínú ọkàn rẹ̀.

24 Ní ọdọdún, olúkúlùkù ẹni tí o wá mú ẹ̀bùn ohun èlò wúrà àti fàdákà àti aṣọ ìbora, ìhámọ́ra, àti tùràrí, àti ẹsin àti ìbaka wá.

25 Sólómónì sì ní ẹgbàajì ilé fún àwọn ẹsin àti kẹ̀kẹ́, àti ẹgbàfà àwọn ẹsin (12,000), tí ó ba mọ́ nínú ìlú kẹ̀kẹ́ àti pẹ̀lú rẹ̀ nínú Jérúsálẹ́mù.

26 Ó sì jọba lórí gbogbo àwọn ọba láti odò títí dé ilé àwọn ará fìlístínì àti títí ó fi dé agbègbè ti Éjíbítì.

27 Ọba sì ṣe fàdákà gẹ́gẹ́ bí ìwọpọ̀ ní Jérúsálẹ́mù gẹ́gẹ́ bí òkúta àti igi kédárì ó sì pọ̀ gẹ́gẹ́ bí igi síkámórè ni ibi pẹ̀tẹ́lẹ̀ gígi.

28 A sì mú àwọn ẹsin Sólómónì láti ilẹ̀ òkèrè láti Éjíbítì àti láti gbogbo ìlú

Ikú Sólómónì

29 Àti gẹ́gẹ́ bí ìyókù iṣẹ́ ìjọba Sólómónì, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn Nátanì wòlíì, àti nínú ìsọtẹ́lẹ̀ Áhíjà ará Sílónì àti nínú ìran Ídò, wòlíì tí o kan Jéróbámù ọmọ Nébátì?

30 Sólómónì jọba ní Jérúsálẹ́mù lórí gbogbo àwọn Ísírẹ́lì fún ogójì ọdún (40)

31 Sólómónì sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín ní ìlú Dáfídì baba rẹ̀, Réhóbóámù, ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34 35 36