1 Jósíà sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́jọ nígbà tí ó jẹ ọba, ó sì dí ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n (31).
2 Ó sì ṣe ohun tí ó dára ní ojú Olúwa, ó sì rìn ọ̀nà baba rẹ̀ Dáfídì, kò sì yà sí ọwọ́ ọ̀tún tàbí òsì.
3 Ní ọdún kẹ́jọ ìjọba rẹ̀, nígbà tí ó sì wà ní ọ̀dọ́mọdé, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí íwá ojú Ọlọ́run Baba Dáfídì. Ní ọdún kéjìlá (12). Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wẹ Júdà àti Jérúsálẹ́mù mọ́ kúrò ní ibi gíga rẹ̀, ère òrìṣà, àti ère yíyá àti ère dídà.
4 Lábẹ́ àpẹẹrẹ àwọn pẹpẹ Bálímù ni a yí lulẹ̀, ó sì fọ́ àwọn ère sí wẹ́wẹ́, ó run àwọn pẹpẹ tí ó wà lórí rẹ̀, wọ́n sì fọ́ túútúú àti àwọn ère dídá, àwọn òrìṣà àti ère dídá. Èyí tí ó fọ́ wọn sì lùúlùú, ó sì gbọ̀n wọ́n sí orí ìsà òkú àti àwọn tí ó ń rúbọ sí wọn.
5 Ó sì sun àwọn egungun àwọn àlùfáà lórí pẹpẹ wọn, Bẹ́ẹ̀ sì ni ó sì wẹ Júdà àti Jrusálẹ́mù mọ́.
6 Ní ìlú Mánásè, Éfíráímù àti Síméónì, àní títí ó fi dé Náfítalì, àti nínú àwọn, ó tú ilé wọn yíkáyíká.
7 Ó sì wó pẹpẹ àti ère òrìṣà lulẹ̀ àti àwọn ère yíyá àti àwọn òrìṣà, ó sì gùn ó sì ti ké gbogbo àwọn ère orí pẹpẹ lulẹ̀ ní gbogbo àyíká Ísírẹ́lì. Lẹ́yìn náà ó padà sí Jérúsálẹ́mù.
8 Ní ọdún kejìdínlógún ìjọba Jósíà ni a ti wẹ ilẹ̀ náà mọ́ àti ilé Olúwa, ó sì rán Ṣáfánì ọmọ Ásálíà àti Màséíà olórí ìlú náà, pẹ̀lú Jóà, ọmọ Jóáhásì, akọ̀wé, láti tún ilé Olúwa Ọlọ́run ṣe.
9 Wọ́n sì lọ sí ọ̀dọ̀ Hílíkíyà olórí àlùfáà, ó sì fún-un ní owó náà tí ó mú wá sí ínú ilé Ọlọ́run, ti àwọn ọmọ Léfì ẹni tí ó jẹ́ aṣọ́-ẹnú-ọ̀nà-ìbòdè ti gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn Ménásè Éfíráímù àti láti ọ̀dọ̀ Àwọn ìyókù Ísírẹ́lì àti ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn Júdà àti Bẹ́ńjámínì wọ́n sì padà sí Jérúsálẹ́mù.
10 Nígbà náà wọn si fi le àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ilé lọ́wọ́, àwọn tí ń ṣe alábojútó iṣẹ́ ilé Olúwa. Àwọn ọkùnrin yìí sì san owó fún àwọn òṣìṣẹ́ tí ó ń tún ṣe, tí wọ́n sì ń ṣìṣẹ́ ní ilé Olúwa.
11 Wọ́n sì tún fi owó fún àwọn ọlọ́nà àti àwọn olùkọ́lé láti ra òkúta gbígbẹ́ àti ìtì igi fún ìsopọ̀ àti igi rírẹ́ fún ìkọ́lé tí ọba Júdà ti gbà láti tẹ́ ilé tí wọ́n ti bàjẹ́.
12 Àwọn ọkùnrin náà ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú òtítọ́ lórí wọn, láti darí wọn ní Jáhátì àti Obadíà, àwọn ọmọ Léfì láti Mérárì, àti Sekaríà àti Mèsúlámù, sọ̀kalẹ̀ láti Kónátì àwọn ọmọ Léfì gbogbo tí ó ní ọgbọ̀n ohun èlò orin.
13 Wọ́n sì ní olórí àwọn aláàárù àti àwọn alábojútó gbogbo àwọn òṣìsẹ́ láti ibisẹ́ si ibisẹ́, díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Léfì sì ní alákọ̀wé, olùtọ́jú àti olùsọ́nà.
14 Nígbà tí wọ́n mú owó náà tí wọ́n mú wá sí ilé Olúwa, Hílkíà àlùfáà sì rí ìwe òfin Olúwa tí a ti fi fún-un láti ọwọ́ Mósè.
15 Hílíkíyà sì wí fún Ṣáfánì akọ̀wé pé, “Èmi ti rí ìwe òfin nínú ilé Olúwa.” Ó sì fi fún Ṣáfánì.
16 Nígbà náà Ṣáfánì sì mú ìwé náà lọ sí ọ̀dọ̀ ọba ó sì ròyìn fún-un. “Àwọn ìjòyè rẹ̀ ń ṣe gbogbo nǹkan tí a ti fi lé wọn lọ́wọ́.
17 Wọ́n ti san owó náà tí ó wà nínú ilé Olúwa wọ́n sì ti fi lé àwọn alábojútó lọ́wọ́ àti àwọn òṣìsẹ́.”
18 Nígbà náà Ṣáfánì akọ̀wé sì sọ fún ọba, “Hílíkíyà àlùfáà ti fún mi ní ìwé.” Ṣáfánì sì kà níwájú ọba.
19 Nígbà tí ọba sì gbọ́ ọ̀rọ̀ òfin, ó sì fa aṣọ rẹ̀ ya.
20 Ó sì pa àṣẹ yìí fún Hílíkíyà, Áhíkámù ọmọ Ṣáfánì, Ábídónì ọmọ Míkà, Ṣáfánì akọ̀wé àti Ásáíà ìránṣẹ́ ọ̀nà.
21 “Ẹ lọ kí ẹ lọ bérè lọ́wọ́ Olúwa fún mi fún àwọn ìyókù Ísírẹ́lì àti Júdà nípa ohun tí wọ́n kọ sínú ìwé yìí tí a ti rí. Títóbi ni ìbínú Olúwa tí ó ti jáde sí orí wa nítorí àwọn baba wa kò ti pa ọ̀rọ̀ Olúwa mọ́, wọn kò sì tíì ṣe gẹ́gẹ́ bí i gbogbo èyí tí a kọ sínú ìwé yìí.”
22 Híkíánì àti àwọn ènìyàn tí a yàn sì lọ láti sọ̀rọ̀ sí àwọn wòlíì Húlídà aya Ṣálúmù ọmọ Tókátì, ọmọ Hásíràh, olùtọ́jú ibi ìkásọsí, ó sì ń gbé ní Jérúsálẹ́mù, ní ìhà kejì.
23 Ó sì wí fún wọn wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì ti sọ, sọ fún àwọn ọkùnrin tí ó rán ọ sí mi pé,
24 ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Èmi yóò sì mú ibi wá sí ìhín yìí àti àwọn ènìyàn rẹ̀ gbogbo ègún tí a kọ sínú ìwé tí wọ́n ti kà níwájú ọba Júdà.
25 Nítorí tí wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀ wọ́n sì ti sun tùràrí sí ọlọ́run mìíràn wọ́n sì ti mú mi bínú pẹ̀lú gbogbo ohun tí wọ́n ti fi ọwọ́ wọn ṣe, ìbínú yóò tú jáde wá sórí ibíyìí, a kì yóò sì paná rẹ̀.’
26 Sọ fún ọba Júdà, ẹni tí ó rán yín láti bèèrè lọ́wọ́ Olúwa, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa ti sọ, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, sọ nípa ọ̀rọ̀ wọ̀n nì tí íwọ gbọ́:
27 Nítorí ọkàn rẹ̀ dúró ìwọ sì rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú Olúwa nígbà tí ó gbọ́ ohun tí ó sọ lórí ibíyìí àti ènìyàn rẹ, nítorí ìwọ rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú mi tí o sì fa aṣọ rẹ ya, tí o sì lọ níwájú mi. Èmi ti gbọ́ tìrẹ ni Olúwa wí.
28 Nísinsinyìí, Èmi ó kó ọ jọ pọ̀ sọ́dọ̀ àwọn baba rẹ, a ó sì sin ọ́ ní àlàáfíà. Ojú rẹ kò sì ní rí gbogbo ibi tí èmi ó mú wá sórí ibíyìí àti lórí àwọn tí ń gbé ibẹ̀.’ ”Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé ìdáhùn rẹ̀ padà sí ọ̀dọ̀ ọba.
29 Nígbà náà ọba sì pe gbogbo àwọn àgbààgbà Júdà jọ àti Jérúsálẹ́mù.
30 Wọ́n sì lọ sókè ní ilé Olúwa pẹ̀lú àwọn ọkùnrin Júdà, àwọn ènìyàn Jérúsálẹ́mù, àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì gbogbo ènìyàn lati ẹní ńlá sí ẹní kékeré, ó sì kà á ní etí wọn gbogbo ọ̀rọ̀ ínú ìwé májẹ̀mú, tí wọ́n ti rí nínú ilé Olúwa.
31 Ọba sì dúró ní ipò rẹ̀ ó sì tún májẹ̀mú dá níwájú Olúwa láti tẹ̀lé Olúwa àti láti pa ofin rẹ̀ mọ́, àti ẹ̀rí rẹ̀ àti àṣẹ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀ àti gbogbo àyà rẹ̀ àti láti pa ọ̀rọ̀ májẹ̀mú tí a kọ sí ínú ìwé yìí.
32 Nígbà náà, ó sì mú kí gbogbo ènìyàn ní Jérúsálẹ́mù àti Bẹ́ńjámínì dúró nínú ẹ̀rí fún ara wọn, àwọn ènìyàn Jérúsálẹ́mù ṣe èyí gẹ́gẹ́ bi májẹ̀mú Ọlọ́run, Ọlọ́run Baba wọn.
33 Jósíà sì kó gbogbo ohun ìríra kúrò nínú gbogbo ìlú tí ń ṣe ti àwọn tí ó wà ní Ísírẹ́lì, ó sì mú kí gbogbo àwọn tí ó wà ní Ísírẹ́lì sin Olúwa Ọlọ́run wọn gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe wà láyè wọn, kò yà kúrò láti máa tọ Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn lẹ́yìn.