2 Kíróníkà 20 BMY

Jéhóṣáfátì Pa Móábù Àti Ámónì Run

1 Lẹ́yìn èyí, àwọn ọmọ Móábù àti àwọn ọmọ Ámónì àti díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Édómù wá láti gbé ogun tọ Jéhóṣáfátì wá.

2 Àwọn díẹ̀ nínú àwọn ọkùnrin wá láti sọ fún Jéhóṣáfátì, “Àwọn ọ̀pọ̀ ọ̀wọ́ ogun ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti Édómù, láti apákejì òkun. Ó ti wà ní Hásásónì Támárì náà” (èyí ni wí pé, Énígédì).

3 Ní ìdágìrì, Jéhóṣáfátì pinnú láti wádìí lọ́wọ́ Olúwa, ó sì kéde ààwẹ̀ kíákíá fún gbogbo Júdà.

4 Àwọn ènìyàn Júdà sì kó ara wọn jọpọ̀ láti wá ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Olúwa; pẹ̀lúpẹ̀lú, wọ́n wá láti gbogbo ìlú ní Júdà láti wá a.

5 Nígbà náà Jéhóṣáfátì dìde dúró níwájú àpèjọ Júdà àti Jérúsálẹ́mù ní ilé Olúwa níwájú àgbàlá tuntun.

6 O sì wí pé:“Olúwa, Ọlọ́run àwọn bàba wa, ìwọ kì ha ṣe Ọlọ́run tí ń bẹ ní ọ̀run? Ìwọ ń ṣe alákòóṣo lórí gbogbo ìjọba àwọn orílẹ̀ èdè. Agbára àti ipá ń bẹ ní ọwọ́ rẹ, kò sì sí ẹnìkan tí ó lè kò ọ́ lójú.

7 Ìwọ Ọlọ́run wa, ṣé o kò lé àwọn olùgbé ilẹ̀ yìí jáde níwajú àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì tí o sì fi fún àwọn ọmọ Ábúráhámù ọ̀rẹ́ rẹ láéláé?

8 Wọ́n ti ń gbé nínú rẹ̀ wọ́n sì ti kọ́ sínú rẹ ibi mímọ́ fún orúkọ rẹ wí pé,

9 ‘Tí ibi bá wá sí orí wa, bóyá idà ìjìyà tàbí àjàkálẹ̀-àrùn àwọn yóò dúró níwájú rẹ níwájú ilé yìí tí ń jẹ́ orúkọ rẹ, àwa yóò sì sunkún jáde, ìwọ yóò sì gbọ́ wa. Ìwọ yóò sì gbà wá là?’

10 “Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí àwọn ọkùnrin nìyí láti Ámónì, Móábù àti òkè Séírì, agbègbè ibi ti ìwọ kò ti gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láyè láti gbógun tì nígbà tí wọn wá láti Éjíbítì; Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn, wọn kò sì pa wọ́n run.

11 Sì kíyèsí i, bí wọ́n ti san án pada fún wa; láti wá lé wa jáde kúrò nínú ìní rẹ, tí ìwọ ti fi fún wa láti ní.

12 Ọlọ́run wa, ṣé ìwọ kò ní ṣe ìdájọ́ fún wọn? Nítorí àwa kò ní agbára láti dojú kọ àwọn ọ̀pọ̀ ogun ńlá yìí tí ń bọ̀ wá kó wa. Àwa kò mọ̀ ohun tó yẹ ká ṣe, ṣùgbọ́n ojú wa wà ní ọ̀dọ̀ rẹ.”

13 Gbogbo àwọn ọkùnrin Júdà, pẹ̀lú àwọn aya wọn àti ọmọ wọn àti àwọn kékèké, dúró níbẹ̀ níwájú Olúwa.

14 Nígbà náà, ẹ̀mí Olúwa sì bà lé Jáhásíẹ̀lì ọmọ Sékáríà, ọmọ Bénáyà, ọmọ Jéíèlì, ọmọ Mátaníyà ọmọ Léfì àti ọmọ Ásáfù, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe dìde dúró láàrin àpèjọ ènìyàn.

15 Ó sì wí pé, “Ẹ tẹ́tí sílẹ̀, ọba Jéhóṣáfátì àti gbogbo àwọn tí ń gbé ní Júdà àti Jérúsálẹ́mù! Èyí ní ohun tí Olúwa sọ wí pé kí a ṣe: ‘Ẹ má ṣe bẹ̀rù tàbí fòyà nítorí ọ̀pọ̀ ogun ńlá yìí. Nítorí, ogun ìjà náà kìí ṣe ti yín, ṣùgbọ́n ti Ọlọ́run ni.

16 Ní ọla, ẹ sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wọ́n lọ, wọn yóò gòkè pẹ̀lú ibi ṣíṣe wa, ẹ̀yin yóò sì rí wọn ní ìpẹ̀kun odò náà, níwájú ihà Jérúẹ́lì.

17 Ẹ̀yin kò ní láti bá ogun yìí jà. Ẹ dúró ní àyè yín; Ẹ dúró jẹ́ẹ́ kí ẹ sì rí ìgbàlà Olúwa tí yóò fi fún yín, ìwọ Júdà àti Jérúsálẹ́mù. Ẹ má ṣe bẹ̀rù; Ẹ má sì ṣe fòyà. Ẹ jáde lọ láti lọ dojú kọ wọ́n ní ọ̀la, Olúwa yóò sì wà pẹ̀lú yín.’ ”

18 Jóhóṣáfátì tẹ orí rẹ̀ ba sílẹ̀ pẹ̀lú ojú rẹ̀, àti gbogbo àwọn ènìyàn Júdà àti Jérúsálẹ́mù wólẹ̀ níwájú láti sin Olúwa.

19 Nígbà náà díẹ̀ lára àwọn ọmọ Léfì àti àwọn ọmọ Kóhátì àti àwọn kórì sì dìde dúró wọ́n sì sin Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, pẹ̀lú ohùn ariwo ńlá.

20 Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù wọ́n jáde lọ sí ihà Tékòa. Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń jáde lọ, Jéhóṣáfátì dìde dúró ó sì wí pé, “Ẹgbọ́ mi, Júdà àti ènìyàn Jérúsálẹ́mù! Ẹ ní ìgbàgbọ́ ninú Olúwa Ọlọ́run yín ẹ̀yin yóò sì borí, ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn wòlíì rẹ̀ ẹ̀yìn yóò sì ṣe rere.”

21 Lẹ́yìn ìgbà tí ó bá àwọn ènìyàn náà gbèrò tán, Jéhóṣáfátì yàn wọ́n láti kọrin sí Olúwa àti láti fi ìyìn fún ẹwà ìwà mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ó tì ń jáde lọ sí ìwájú ogun ńlá náà, wí pé:“Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa,nítorí àànú rẹ̀ dúró títí láéláé.”

22 Bí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí kọrin àti ìyìn, Olúwa rán ogun ẹ́yìn sí àwọn ọkùnrín Ámónì àti Móábù àti òkè Séírì tí ó ń gbógun ti Júdà, wọ́n sì kọlù wọ́n.

23 Àwọn ọkùnrin Ámónì àti Móábu dìde dúró sí àwọn ọkùnrin tí ń gbé òkè Séírì láti pa wọ́n run túútúú. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n sì ti pa àwọn ọkùnrin làti òkè Séírì, wọ́n sì ran ra wọn lọ́wọ́ láti pa ara wọn run.

24 Nígbà tí Àwọn èníyàn Júdà jáde sí ìhà ilé ìsọ́ ní ihà, wọn ń wo àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn, òkú nìkan ni wọ́n rí tí ó ṣubú sí ilẹ̀, kò sì sí ẹnìkan tí ó rí àyè sá.

25 Bẹ́ẹ̀ ni Jéhóṣáfatì ati àwọn èniyàn rẹ̀ lọ láti kó ìkógun wọn, wọ́n sì rí lára wọn ọ̀pọ̀ iyebíye ọrọ̀ púpọ̀, ó sì ju èyí tí wọ́n lè kó lọ. Ọ̀pọ̀ ìkógun sì wà níbẹ̀, èyí tí ó gbà wọ́n ní ọjọ́ mẹ́ta láti gbà pọ̀.

26 Ní ọjọ́ kẹ̀rin, wọn kó ara jọpọ̀ ní àfonífojì ìbùkún, níbi tí wọ́n ti ń fi ìbùkún fún Olúwa. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń pe ibẹ̀ ní àfonífojì ìbùkún títí di òní.

27 Nígbà náà wọ́n darí pẹ̀lú Jéhóṣáfátì, gbogbo àwọn ènìyan Júdà àti Jérúsálẹ́mù padà pẹ̀lú ayọ̀ sí Jérúsálẹ́mù, nítorí Olúwa ti fún wọn ní ìdí láti yọ̀ lórí àwọn ọ̀tá wọn.

28 Wọ́n sì wọ Jérúsálẹ́mù, wọ́n sì lọ sí ilé Olúwa pẹ̀lú ohun èlò orin àti dùùrù àti ipè.

29 Ìbẹ̀rù Ọlọ́run wá si orí gbogbo ìjọba ilẹ̀ náà nígbà tí wọ́n gbọ́ bí Olúwa ti bá àwọn ọ̀ta Ísírẹ́lì jà.

30 Bẹ́ẹ̀ ni ìjọba Jéhóṣáfátì sì wà ní àlàáfíà, nítorí Ọlọ́run rẹ̀ ti fún-un ni ìsinmi ní gbogbo àyíká.

Òpin Ìjọba Jéhóṣáfátì

31 Báyìí ni Jéhóṣáfátì jọba lórí Júdà. Ó sì jẹ́ ẹni ọdún márùndínlógójì. Nígbà tí ó di ọba Júdà, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Ásúbà ọmọbìnrin Ṣílíhì.

32 Ó sì rin ọ̀nà baba rẹ̀ Ásà kò sì yà kúrò nínú rẹ̀, ó si ṣe èyí tí ó tọ́ ní ojú Olúwa.

33 Ní ibi gíga, pẹ̀lúpẹ̀lù, kò mu wọn kúrò, gbogbo àwọn ènìyàn náà kò sì fi ọkan wọn fún Ọlọ́run àwọn baba wọn.

34 Ìyòókù iṣẹ́ ìjọba Jéhóṣáfátì, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ni a kọ sí inú ìwé ìtàn ti Jéhù ọmọ Hánánì, tí a kọ sí inú ìwé àwọn ọba Ísírẹ́lì.

35 Nígbà tí ó yá, Jehóṣáfátì ọba Júdà da ara rẹ̀ pọ̀ pẹ̀lú Áhásáyà, ọba Ísírẹ́lì, ẹni tí ó jẹ̀bi búburú ìwà.

36 Ó sì gbà pẹ̀lú rẹ̀ láti kan okọ̀ láti lọ sí Táríṣísì, lẹ́yìn èyí wọ́n kan ọkọ̀ ní Ésíonì-Gébérì.

37 Élísérì ọmọ Dáfídì ti Máréṣà sọtẹ́lẹ̀ sí Jóhóṣáfátì, wí pe, “Nítorí tí ìwọ ti da ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ Áhásáyà, Olúwa yóò pa ohun ti iwọ ti ṣe run.” Àwọn ọkọ̀ náà sì fọ́, wọn kò sì le lọ sí ibi ìtajà.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34 35 36