2 Kíróníkà 13:11-17 BMY

11 Ní àràárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́, wọ́n gbé ọrẹ sísun àti tùràrí olóòórùn dídùn síwájú Olúwa. Wọ́n gbé àkàrà jáde sórí tábìlì àsè mímọ́, wọ́n sì tan iná sí àwọn fìtílà lórí ìdúró ọ̀pá fìtílà wúrà ní gbogbo ìrọ̀lẹ́. A ń pa àṣẹ Olúwa Ọlọ́run wa mọ́. Ṣùgbọ́n ìwọ ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀.

12 Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa; òun ni olórí wa. Àwọn àlùfáà rẹ̀ pẹ̀lú fèrè wọn yóò dún dídùn ogun sí i yín. Ẹyin ọkùnrin Ísírẹ́lì, Ẹ má ṣe dojú ìjà kọ Olúwa Ọlọ́run baba a yín nítorí ẹ̀yin kì yóò yege.”

13 Nísinsìn yìí, Jéróbóámù ti rán àwọn ọ̀wọ́ ogun lọ yíká láti jagun ẹ̀yìn. Kí ó lè jẹ́ pé, tí òun bá wà ní wájú Júdà, bíba ní bùba á wà ní ẹ̀yìn wọn.

14 Nígbà tí Júdà sì bojúwo ẹ̀yìn, sì kíyèsi i, ogun ń bẹ níwáju àti lẹ́yìn, wọn sì ké pe Olúwa, àwọn àlùfáà sì fun ìpè

15 Olúkúlùkù, ọkùnrin Júdà sì hó: ó sì ṣe, bí àwọn ọkùnrin Júdà sì ti hó, ni Ọlọ́run kọlu Jéróbóámù àti gbogbo Ísírẹ́lì níwájú Ábíjà àti Júdà.

16 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sálọ kúrò níwájú Júdà, Ọlọ́run sì fi wọ́n lé wọn lọ́wọ́.

17 Ábíjà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ fi ìdàmú ńlá jẹ wọ́n ní ìyà, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ọkùnrin tí a yàn ṣubú ní pípa nínú Ísírẹ́lì.