16 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sálọ kúrò níwájú Júdà, Ọlọ́run sì fi wọ́n lé wọn lọ́wọ́.
17 Ábíjà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ fi ìdàmú ńlá jẹ wọ́n ní ìyà, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ọkùnrin tí a yàn ṣubú ní pípa nínú Ísírẹ́lì.
18 Báyìí ni a rẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ ní àkókò náà, àwọn ọmọ Júdà sì borí nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn.
19 Ábíjà sì lépa Jéróbóámù, ó sì gba ìlú lọ́wọ́ rẹ̀, Bétílì pẹ̀lú àwọn ìlú rẹ̀, àti Jeṣánà pẹ̀lú àwọn ìlú rẹ̀, àti Éufúráímù pẹ̀lú àwọn ìlú rẹ̀.
20 Bẹ́ẹ̀ ní Jéróbóámù kò sì tún ní agbára mọ́ ní ọjọ́ Ábíjà. Olúwa sì lù ú ó sì kú.
21 Ábíjà sì di alágbára, ó sì gbé obìnrin mẹ́talá ní ìyàwó, ó sì bi ọmọkùnrin méjìlélógún, àti ọmọbìnrin mẹ́rìndinlógún.
22 Àti ìyókù ìṣe Ábíjà, àti ìwà rẹ̀, àti iṣẹ́ rẹ̀, a kọ wọ́n sínú ìwé ìtumọ̀ Ididì, wòlíì Ídò.