1 Nísinsin yìí Jéhóṣáfátì sì ní ọrọ̀ àti ọlá púpọ̀, ó sì dá àna pẹ̀lú Áhábù nípa fífẹ́ ọmọ rẹ̀.
2 Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, ó sọ̀kalẹ̀ láti lọ bá Áhábù lálejò ní Saaríà. Áhábù sì pa àgùntàn àti màlúù púpọ̀ fún àti àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ó sì rọ̀ọ́ láti dojú ìjà kọ Ramótì Gílíádì.
3 Áhábù ọba Ísírẹ́lì sì béèrè lọ́wọ́ ọba Jèhóṣáfátì, ọba Júdà pé, “Ṣé ìwọ yóò lọ pẹ̀lú mi sí Rámótì Gílíádì?”Jehóṣáfátì sì dá a lóhùn pé, “Èmi wà gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe wà, àti àwọn ènìyàn mi gẹ́gẹ́ bí ènìyàn rẹ àwa yóò pẹ̀lú rẹ ninú ogun naà”
4 Ṣùgbọ́n Jehóṣáfátì náà sì tún wí fún ọba Ísírẹ́lì pé, “Kọ́kọ́ béèrè lọ́wọ́ Olúwa.”
5 Bẹ́ẹ̀ ọba Ísírẹ́lì kó àwọn wòlíì papọ̀, irínwó (4,000) ọkùnrin ó sì bi wọ́n pé, “Kí àwa kí lọ sí ogun Rámótì Gélíádì tàbi kí èmi kí ó jọ̀wọ́ rẹ?”“Lọ,” wọ́n dáhùn, “nítorí tí Olúwa yóò fi lé ọba lọ́wọ́.”