12 Ìránsẹ́ tí ó ti lọ pe Míkáyà sì wí fún un pé, “Ẹ wò ó, gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin kan àti òmíràn wòlíì fi ẹnu kan sọ rere fún ọba. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ kí ó níí ṣe pẹ̀lú ti wa, kí o sì sọ rere.”
13 Ṣùgbọ́n Míkáyà wí pe, “Gẹ́gẹ́ bí ó ti dájú pé Olúwa ń bẹ láàyè, èmi yóò sọ ohun tí Ọlọ́run mi sọ.”
14 Nígbà tí ó dé, ọba béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, “Míkáyà, se kí àwa ki ó lọ sí ogun ti Rámótì Gílíádì, tàbí kí àwa kí ó fàsẹ́yìn?”“Ẹ dojú kọ wọ́n kí ẹ sì ṣẹ́gun.” Ó dahùn, “nítorí a ó fi wọ́n lé yín lọ́wọ́.”
15 Ọba sì wí fún-un pé, “Ìgbà mélòó ni èmi ó fi ọ́ búra láti sọ ohun kan fún mi bí kò ṣe ọ̀rọ̀ òtítọ́ ní orúkọ Olúwa?”
16 Nígbà náà Míkáyà dáhùn, “Mo rí gbogbo Ísírẹ́lì fọ́n káàkiri lórí àwọn òkè, bí àgùntàn tí kò ní olùsọ́. Olúwa sì wí pé, ‘Àwọn ènìyàn wọ̀nyí kò ní ọ̀gá. Jẹ́ kí olúkúlùkù lọ sí ilé ní àlàáfíà.’ ”
17 Ọba Ísírẹ́lì wí fún Jéhóṣáfátì pé, “Ṣe èmi kò sọ fún ọ wí pé òun kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere kankan nípa mi rí, ṣùgbọ́n búburú nìkan?”
18 Mikáyà tẹ̀ṣíwájú pé, “Nítorí náà, gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa: Mo rí Olúwa jòkó lórí ìtẹ́ rẹ̀ gbogbo ogun ọ̀run sì dúró lápá ọ̀tún àti lápá òsì.