1 Sólómónì pinnu láti kọ́ ilé fún orúkọ Olúwa àti ilé kan fún ìjọba rẹ̀
2 Sólómónì sì yan ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà àádọ́rin àwọn (70,000) ọkùnrin láti ru ẹrù àti ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ọgọ́rin àwọn (80,000) ọkùnrin gẹ́gẹ́ bi olùgé-òkúta ní àwọn òkè àti ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógójì (36,000) gẹ́gẹ́ bí àwọn alábojútó lórí wọn.
3 Sólómónì rán iṣẹ́ yìí sí Hírámíà ọba Tírè:“Rán àwọn igi kédárì sí mi gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe fún baba à mi Dáfídì. Nígbà tí ó fi igi kédárì ránsẹ́ sí i láti kọ́ ààfin tí ó ń gbé.
4 Nísinsin yìí, èmi n kọ́ ilé kan fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run mi àti láti yà á sí mímọ́ fún un àti láti sun tùràrí olóòórùn dídùn níwájú rẹ̀, fún gbígbé àkàrà-ìfihàn ìgbàkúgbà, àti fún síse ẹbọ sísun ní gbogbo àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ àti ní ọjọọjọ́ ìsinmi àti òṣùpá tuntun àti ní àpèjọ Olúwa Ọlọ́run wa. Èyí ni àsẹ fún Ísírẹ́lì láéláé.