2 Kíróníkà 2:10-16 BMY

10 Èmi yóò fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ọkùnrin onígi tí ó ń gé rírẹ́ náà ni ẹgbẹ̀rún kórísì (1,000), àlìkámà ilẹ̀ àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún (20,000) kórísì ti bálì; ẹgbẹ́rùn lọ́nà (20,000) ogún ìwẹ̀ ọtí wáìnì àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún ìwẹ̀ òróró Ólífì.”

11 Hírámù ọba Tírè fèsì padà nípasẹ̀ ìwé sí Sólómónì:“Nítorí tí Olúwa fẹ́ràn àwọn ènìyàn rẹ̀, ó ti se ọ́ ní ọba wọn.”

12 Hírámì fi kún un pe:“Ìyìn ni fún Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí ó dá ọ̀run òun ayé! O ti fún ọba Dáfídì ní ọmọ tí ó gbọ́n, tí ó kún fún ìmọ̀ àti àkíyèsí, tí yóò kọ́ ilé fún Olúwa àti ààfin fún ara rẹ̀.

13 “Èmi ń rán Húrámì-Abi, sí ọ ọkùnrin tí ó kún fún ìmọ̀ ńlá,

14 Ẹni tí ìyá rẹ̀ wá láti Dánì àti tí Baba a rẹ̀ wá láti Tírè. A kọ́ ọ láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wúrà àti igi, àti pẹ̀lú àwọ̀ àlùkò àti àwọ̀ ọ̀run àti àwọ̀ pupa fòò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ tí ó dára. Ó ní ìmọ̀ nínú gbogbo oríṣìí iṣẹ́ fínfín. Ó sì le ṣe àwárí irú ẹ̀yà kẹ́yà tí a bá fún un. Òun yóò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn oníṣọ̀nà pẹ̀lú àwọn ènìyàn Olúwa mi, Dáfídì baba a rẹ.

15 “Nísinsin yìí, jẹ́ kí Olúwa mi rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní àlìkámọ̀ àti bálì àti òróró Ólífì náà àti ọtí tí ó ti ṣe ìlérí.

16 Àwa yóò sì gé gbogbo àwọn ìtí igi láti Lébanónì tí ìwọ yóò lò pẹ̀lú a ó gbé wọn fò lójú omi òkun lọ sí Jópà. Lẹ́yìn náà ìwọ lè kó wọn gòkè lọ sí Jérúsálẹ́mù.”