18 Nígbà náà, Jéhóiádà tẹ àwòrán ilé Olúwa sí ọwọ́ àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ará Leì ẹni tí Dáfídì ti fi ṣe iṣẹ́ ní ilé Olúwa láti tẹ ọrẹ sísun ti Olúwa bí a ti kọ ọ́ nínú òfin Mósè. Pẹ̀lú ayọ̀ Àti orin kíkọ, gẹ́gẹ́ bí Dáfídì ti pàsẹ.
19 Ó mú àwọn olùsọ́nà wà ni ipò ìdúró ní ẹnu odi ilé Olúwa kí ẹni aláìmọ́ nínú ohun-kóhun kó má baà wọlé.
20 Ó mú pẹ̀lú rẹ̀ àwọn alákóso ọrọrún, Àwọn eni-ọlá, àwọn olórí àwọn ènìyàn àti gbogbo àwọn Ènìyàn ilẹ̀ náà. Ó sì mú ọba sọ̀kalẹ̀ wá láti ilé Olúwa. Wọ́n lọ sínú Ààfin láti ẹnu òde tòkè. Wọ́n sì fi ọba jókoó lórí ìtẹ́.
21 Gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà sì ń yọ̀. Ìlú naà sì dákẹ́ rọ́rọ́. Nítorí tí a pa Ataláyà pẹ̀lú idà.